+ -

عَنْ مَيْمُونَةُ أُمِّ المؤمِنينَ رضي الله عنها قَالتْ:
وَضَعْتُ لِلنَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ غُسْلًا، فَسَتَرْتُهُ بِثَوْبٍ، وَصَبَّ عَلَى يَدَيْهِ، فَغَسَلَهُمَا، ثُمَّ صَبَّ بِيَمِينِهِ عَلَى شِمَالِهِ، فَغَسَلَ فَرْجَهُ، فَضَرَبَ بِيَدِهِ الأَرْضَ، فَمَسَحَهَا، ثُمَّ غَسَلَهَا، فَمَضْمَضَ وَاسْتَنْشَقَ، وَغَسَلَ وَجْهَهُ وَذِرَاعَيْهِ، ثُمَّ صَبَّ عَلَى رَأْسِهِ وَأَفَاضَ عَلَى جَسَدِهِ، ثُمَّ تَنَحَّى، فَغَسَلَ قَدَمَيْهِ، فَنَاوَلْتُهُ ثَوْبًا فَلَمْ يَأْخُذْهُ، فَانْطَلَقَ وَهُوَ يَنْفُضُ يَدَيْهِ.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 276]
المزيــد ...

Lati ọdọ Maymūna iya gbogbo mumini - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Mo gbe omi iwẹ fun Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mo si fi aṣọ kan bo o, o wa da omi si ọwọ rẹ mejeeji, ti o si fọ wọn, lẹyin naa ni o fi ọwọ ọtun rẹ da omi si ọwọ osi, o si fọ abẹ rẹ, ni o wa fi ọwọ rẹ lu ilẹ, ti o si nu un, lẹyin naa ni o fọ ọ, ni o wa fi omi yọ ẹnu o si tun fin in si imu, o si tun fọ oju rẹ ati apa rẹ mejeeji, lẹyin naa ni o da omi si ori rẹ ti o si da a si ara rẹ, lẹyin naa ni o bọ́ sí ẹgbẹ kan, ti o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji, ni mo wa fun un ni aṣọ kan ti ko si gba a, ni o wa jade lẹni ti o n gbọn owo rẹ mejeeji.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 276]

Àlàyé

Iya awọn olugbagbọ Maimuunah- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa alaye iwẹ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- latara janaba, nigba ti o gbe omi fun un lati fi wẹ, ti o si da gaga kan bo o, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe awọn nnkan ti o n bọ yìí:
Akọkọ: O da omi si ọwọ rẹ mejeeji o si fọ mejeeji ṣíwájú ki o to ti mejeeji bọ inu igba.
Ikeji: O da omi pẹlu ọwọ rẹ ọtun lori osi o si fọ abẹ rẹ; lati mọ ọn kuro nibi nnkan ti o ba lẹ̀ mọ́ ọn ninu oripa janaba.
Ikẹta: O fi ọwọ rẹ lu ilẹ̀, o si nù ún, lẹ́yìn náà o fọ ọ lati le mu ẹgbin kuro nibẹ.
Ikẹrin: O fi omi yọ ẹnu rẹ: pẹlu ki o fi omi si ẹnu rẹ, o si mi I, o yi i lẹyin naa o tu u, o fin omi simu; pẹlu ki o fi omi simu rẹ pẹlu èémí rẹ, lẹyin naa o mu u jade lati fi mọ ọn.
Ikarun-un: O fọ oju rẹ ati awọn apa rẹ mejeeji.
Ikẹfa: O da omi si ori rẹ.
Ikeje: O da omi si awọn toku ninu ara rẹ.
Ikẹjọ: O kuro nibi aaye rẹ o si fọ ẹsẹ rẹ mejeeji ní ibòmíì tí kò tíì fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Lẹyin naa, o mu aṣọ kan wa fun un lati nu ara rẹ pẹlu rẹ, ṣùgbọ́n ko gba a, o bẹ̀rẹ̀ si n nu omi kuro lara rẹ pẹlu ọwọ rẹ ti o si n gbọn ọn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Akolekan awọn iyawo Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu alaye kúlẹ̀kúlẹ̀ ti o kéré jù lọ ninu isẹmi aye rẹ; lati fi jẹ ẹkọ fun ijọ Anabi.
  2. Alaye iwẹ yìí jẹ ọkan ninu awọn ọna ti o fi ẹsẹ rinlẹ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi bi a ṣe maa n wẹ iwẹ ti o pe latara janaba, ṣùgbọ́n ọna ti o to ni ki o fi omi kari ara rẹ pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fifin in simu.
  3. Fifi aṣọ nu ara tabi fifi i silẹ lẹyin iwẹ tabi aluwala jẹ nnkan ti o tọ́.