عَنْ صُهَيْبٍ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«عَجَبًا لِأَمْرِ الْمُؤْمِنِ، إِنَّ أَمْرَهُ كُلَّهُ خَيْرٌ، وَلَيْسَ ذَاكَ لِأَحَدٍ إِلَّا لِلْمُؤْمِنِ، إِنْ أَصَابَتْهُ سَرَّاءُ شَكَرَ، فَكَانَ خَيْرًا لَهُ، وَإِنْ أَصَابَتْهُ ضَرَّاءُ صَبَرَ، فَكَانَ خَيْرًا لَهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2999]
المزيــد ...
Lati ọdọ Suhayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Eemọ ni alamọri mumini, dajudaju gbogbo alamọri rẹ oore ni, iyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini, ti idunu ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ, ti yio si jẹ oore fun un, ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru, ti yio si tun jẹ oore fun un».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2999]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe eemọ nipa ọrọ mumini ati awọn iṣesi rẹ ni ti daadaa; ìyẹn ni pe gbogbo ìṣesí rẹ patapata ni oore, ti ìyẹn o si si fun ẹnikankan ayaafi mumini; Ti daadaa ba ṣẹlẹ si i yio dupẹ fun Ọlọhun lori rẹ; ti yio si gba ẹsan pẹlu ọpẹ dida, Ti inira ba si tun ṣẹlẹ si i yio ṣe suuru ti yio si tun retí ẹsan lọdọ Ọlọhun, ti yio si tun gba ẹsan suuru, nitori naa inu ẹsan ni o wa ni gbogbo ìṣesí rẹ.