عَنْ أَبِي سَعِيدٍ الخُدْرِيِّ رضي الله عنه أَنَّهُ سَمِعَ رَسُولَ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِذَا رَأَى أَحَدُكُمُ الرُّؤْيَا يُحِبُّهَا فَإِنَّهَا مِنَ اللَّهِ، فَلْيَحْمَدِ اللَّهَ عَلَيْهَا وَلْيُحَدِّثْ بِهَا، وَإِذَا رَأَى غَيْرَ ذَلِكَ مِمَّا يَكْرَهُ، فَإِنَّمَا هِيَ مِنَ الشَّيْطَانِ، فَلْيَسْتَعِذْ مِنْ شَرِّهَا، وَلاَ يَذْكُرْهَا لِأَحَدٍ، فَإِنَّهَا لَنْ تَضُرَّهُ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 7045]
المزيــد ...
Lati ọdọ baba Sa'eed Al-khudiriy - Ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - Ó ní oun gbọ́ tí Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa ba - tí ńsọ bayii pé:
"Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 7045]
Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.