Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn hadiisi

Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a
عربي الإنجليزية الأوردية
Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a
عربي الإنجليزية الأوردية