عَنْ أَبِي قَتَادَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«الرُّؤْيَا الصَّالِحَةُ مِنَ اللَّهِ، وَالحُلُمُ مِنَ الشَّيْطَانِ، فَإِذَا حَلَمَ أَحَدُكُمْ حُلُمًا يَخَافُهُ فَلْيَبْصُقْ عَنْ يَسَارِهِ، وَلْيَتَعَوَّذْ بِاللَّهِ مِنْ شَرِّهَا، فَإِنَّهَا لاَ تَضُرُّهُ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3292]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Qatada - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pé: Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ pé:
Lati ọdọ Ọlọhun ni ala daada ti nwa, bẹẹ ni láti ọdọ èṣù (Satani) ni ala burúkú ti nwa, ti ẹnikan nínú yín bá lá ala tí o se idẹruba fun un, ki o yáa fẹ atẹgun itọ ẹnu rẹ sí apá òsì, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburú ala náà, ti o ba se bẹẹ dájúdájú ala náà kòní kó ìnira ba a".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3292]
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) fún wa niro pé ala daada ti o dun ni ninu láti ojú orun lati ọdọ Ọlọhun ni ti nwa, bẹẹ ni alakala ti ko da ti o si nbani nínú jẹ, lati ọdọ èṣù ni ti nwa.
Ẹni k'ẹni ti o bá lala ri nkan ti kò wu u, ki o ya tutọ sí apá òsì rẹ, ki o si wa isọra pẹlu Ọlọhun nibi aburu ala naa, ala náà ko nii ko aburú ba nitoripe Ọlọhun ti fi gbolohun ti o sọ yẹn se okunfa àkóyọ nibi nkan ti kò fẹ ti o le t'ara ala tí o la ṣẹlẹ.