عن عائشة رضي الله عنها قالت: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«السِّوَاكُ مَطْهَرَةٌ لِلْفَمِ، مَرْضَاةٌ لِلرَّبِّ».

[صحيح] - [رواه النسائي وأحمد] - [مسند أحمد: 24203]
المزيــد ...

Lati ọdọ Aisha - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pé:
"Pákò jẹ́ imọtoto fun ẹnu, ó sì jẹ́ okunfa iyọnu Oluwa".

[O ni alaafia] - [Nasaa'iy ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Musnad ti Ahmad - 24203]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ fún wa pé ìmáa ṣe imọtoto eyín pẹlu igi araak (pákò) tabi iru rẹ̀, ó máa n fọ ẹnu mọ́ tonitoni kuro nibi awọn idọti ati oorun tí kò dara ni, ati pé ó jẹ́ ọkan ninu awọn okunfa iyọnu Ọlọhun si ẹru Rẹ̀; nítorí pé ó jẹ́ ìtẹ̀lé ti Ọlọ́hun àti ìdáhùn sí àṣẹ Rẹ̀, ati nítorí pé ìmọ́tótó tí Ọlọ́hun Ọba nífẹ̀ẹ́ sí wà ninu rẹ̀.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọlá ti n bẹ fún imaa run pákò, ati pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n gba awọn ijọ rẹ̀ niyanju lati maa run pákò lọpọlọpọ ìgbà.
  2. Lílo igi araak lati fi run pákò ló lọ́lá jùlọ, àmọ́ lílo búrọ́ọ̀ṣì ati ọṣẹ ifọyin máa n dipo rẹ̀ ni.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)