عن أبِي هريرة رضي اللَّه عنه: سمعتُ النبِيّ صلى الله عليه وسلم يقول:
«الفِطْرَةُ خمسٌ: الخِتَانُ والاستحدادُ وقصُّ الشَّارِبِ وتقليمُ الأظفارِ وَنَتْفُ الآبَاطِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5891]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“Adamọ marun-un lo jẹ: Dida abẹ ati fifa irun abẹ ati gige tubọmu ati gige awọn èékánná ati fifa irun abiya”.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5891]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe awọn iwa marun-un kan n bẹ ninu ẹsin Isilaamu ati ninu sunnah awọn ojiṣẹ:
Akọkọ nibẹ ni: Dida abẹ, oun ni gige awọ ti o lekun lori nnkan ọmọkunrin lori adenderi, ati gige ori awọ ti o wa lori oju ara obinrin lori aye ibi ti nnkan ọmọkunrin maa n wọle si.
Ikeji nibẹ ni: Fifa irun abẹ, oun ni irun oju ara ti o wa ni àyíká oju ara.
Ikẹta nibẹ ni: Gige tubọmu, oun ni gige nnkan ti o hù jade lori ete ọkunrin oke nibi ti ete ti maa hàn.
Ikẹrin nibẹ ni: Gige awọn èékánná.
Ikarun-un nibẹ ni: Gige irun abiya.