عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه أَنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«بَادِرُوا بِالْأَعْمَالِ فِتَنًا كَقِطَعِ اللَّيْلِ الْمُظْلِمِ، يُصْبِحُ الرَّجُلُ مُؤْمِنًا وَيُمْسِي كَافِرًا، أَوْ يُمْسِي مُؤْمِنًا وَيُصْبِحُ كَافِرًا، يَبِيعُ دِينَهُ بِعَرَضٍ مِنَ الدُّنْيَا».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 118]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de, ti ọmọniyan o ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, ti yio ta ẹsin rẹ tori adun aye ti ko nii pẹ tan.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 118]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe mumini ni ojukokoro pẹlu yiyara ati pipọ ni ṣíṣe awọn iṣẹ oloore siwaju nínira rẹ ati kiko airoju kuro nibẹ latari dide awọn fitina ati iruju ti yio dena rẹ, ti yio si ṣẹri àwọn kúrò nibẹ, ati pe okunkun kan ni ti o da bi okunkun oru, ti ododo ati irọ maa dapọ nibẹ, ti yio si le fun awọn eeyan lati ṣe iyatọ laarin mejeeji, ati pe latari lile rẹ (fitina) ọmọniyan o nii mọ nǹkan ti o fẹ ṣe, débi pe yio ji ni mumini ti yio si di alẹ ni keferi, tabi ki o di alẹ ni mumini ki o si ji ni keferi, yio fi ẹsin rẹ silẹ fun adun aye ti yio tan.