عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ قَالَ: قَالَ النَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«السَّاعِي عَلَى الأَرْمَلَةِ وَالمِسْكِينِ، كَالْمُجَاهِدِ فِي سَبِيلِ اللَّهِ، أَوِ القَائِمِ اللَّيْلَ الصَّائِمِ النَّهَارَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5661]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira, o sọ pe: Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Oluran awọn opo ati alaini lọwọ, da gẹgẹ bii olugbinyanju soju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n fi oru rẹ dide ti o si n fi ọsan rẹ gba awẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5661]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba n ṣe anfaani fun obinrin ti ọkọ rẹ ku, ti ko ni ẹni kankan ti o maa moju to awọn alamọri rẹ, ati alaini ti o ni bukaata, ti o si n na owo fun wọn ni ẹni ti o n wa ẹsan lọdọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi ẹsan, o da gẹgẹ bii olujagun loju ọna Ọlọhun, tabi ẹni ti o n ki irun ni oru ti ko ki n rẹ ẹ, ati alaawẹ ti ko ki n túnu.