عَنْ أَبِي مُوسَى رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِنَّمَا مَثَلُ الْجَلِيسِ الصَّالِحِ وَالْجَلِيسِ السَّوْءِ كَحَامِلِ الْمِسْكِ وَنَافِخِ الْكِيرِ، فَحَامِلُ الْمِسْكِ: إِمَّا أَنْ يُحْذِيَكَ، وَإِمَّا أَنْ تَبْتَاعَ مِنْهُ، وَإِمَّا أَنْ تَجِدَ مِنْهُ رِيحًا طَيِّبَةً، وَنَافِخُ الْكِيرِ: إِمَّا أَنْ يُحْرِقَ ثِيَابَكَ، وَإِمَّا أَنْ تَجِدَ رِيحًا خَبِيثَةً».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 2628]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
Dajudaju àpèjúwe olubajokoo rere ati olubajokoo burúkú da gẹgẹ bi ẹni ti o gbe almisiki ati eni ti o n fẹ ina alagbẹdẹ ẹni ti o gbe almisiki: Ninu ki o fun ọ nínú ẹ, tabi ninu ki o ra ọjà lọwọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o daa latara rẹ, ati pe ẹni ti o n fẹ iná alagbẹdẹ: Ninu ki o jo aṣọ rẹ, tabi ki o ri oorun ti o buru".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 2628]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi apejuwe lelẹ fun iran meji ninu awọn eniyan:
Iran akọkọ: Alabajokoo ati ọrẹ rere ti o maa tọka lọ sọ́dọ̀ Ọlọhun ati nnkan ti O yọnu si, ti o maa n ṣe iranlọwọ lori itẹle, Ati pe apejuwe rẹ da gẹgẹ bii ẹni ti o n ta almisiki, ninu ki o fun ẹ, tabi ki o ra a lọwọ rẹ, tabi ki o si gbooorun daadaa lati ọdọ rẹ.
Iran keji: Alabajokoo ati ọrẹ burúkú; ti o maa n ṣẹ́rí àwọn ènìyàn kúrò lójú ọ̀nà (ẹ̀sìn) Allāhu, ti o si maa n ṣe ikunlọwọ lori dida awọn ẹṣẹ, ti waa maa ri iṣẹ buburu lọdọ rẹ, ti yoo maa ko eebu ba ẹ nitori mimu u lọrẹ ati iba iru rẹ jokoo, Iru rẹ da gẹgẹ bii alagbẹdẹ ti o n fẹ ina rẹ: ninu ki o jo aṣọ rẹ latara ẹta parapara ina rẹ ti o n fo tẹle ara wọn, tabi ki o ri oorun buruku latara asunmọ rẹ.