+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَلاَ أُحَدِّثُكُمْ حَدِيثًا عَنِ الدَّجَّالِ، مَا حَدَّثَ بِهِ نَبِيٌّ قَوْمَهُ؟ إِنَّهُ أَعْوَرُ، وَإِنَّهُ يَجِيءُ مَعَهُ بِمِثَالِ الجَنَّةِ وَالنَّارِ، فَالَّتِي يَقُولُ إِنَّهَا الجَنَّةُ هِيَ النَّارُ، وَإِنِّي أُنْذِرُكُمْ كَمَا أَنْذَرَ بِهِ نُوحٌ قَوْمَهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3338]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
"Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ, eyi ti o n pe ni alujanna ni ina, mo n ṣekilọ fun yin gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3338]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun awọn saabe rẹ nipa dajjal ati awọn iroyin rẹ ati awọn ami rẹ pẹlu nǹkan ti Anabi kan ko sọ ri ṣíwájú rẹ, ninu ìyẹn ni:
Pe o jẹ olójú kan.
Ati pe dajudaju Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- fi nnkan ti o daa bii alujanna ati ina pẹlu rẹ, ni ibamu si riri oju.
Ṣugbọn alujanna rẹ jẹ iná, ti ina rẹ si jẹ alujanna, ẹni ti o ba tẹle e o maa mu u wọ inu alujanna yii ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n ina ti o n jóni ni, ẹni ti o ba yapa rẹ o maa mu u wọ ina ninu nnkan ti awọn eniyan n ri, ṣùgbọ́n alujanna ti o daa ni, Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣekilọ fun wa kuro nibi wahala rẹ gẹgẹ bi Nuh ṣe ṣekilọ fun ijọ rẹ pẹlu rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi wahala dajjal.
  2. Lila kuro nibi wahala dajjal maa jẹ pẹlu igbagbọ òdodo ati sisadi Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati wiwa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ nibi ataya ikẹyin, ati hiha aayah mẹwaa ninu akọkọ Suratul Kahf.
  3. Ilekoko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori ìjọ rẹ, nigba ti o ṣe alaye fun awọn Musulumi ninu awọn iroyin dajjal ninu nnkan ti Anabi kan ko ṣàlàyé rẹ ri ṣíwájú rẹ.