+ -

عَنْ عَبْدِ اللهِ بْنِ عَمْرِو بْنِ العَاصِ رضي الله عنهما قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«إِنَّ اللهَ سَيُخَلِّصُ رَجُلًا مِنْ أُمَّتِي عَلَى رُءُوسِ الْخَلَائِقِ يَوْمَ الْقِيَامَةِ، فَيَنْشُرُ عَلَيْهِ تِسْعَةً وَتِسْعِينَ سِجِلًّا، كُلُّ سِجِلٍّ مِثْلُ مَدِّ الْبَصَرِ، ثُمَّ يَقُولُ: أَتُنْكِرُ مِنْ هَذَا شَيْئًا؟ أَظَلَمَكَ كَتَبَتِي الْحَافِظُونَ؟ فَيَقُولُ: لَا يَا رَبِّ، فَيَقُولُ: أَفَلَكَ عُذْرٌ؟ فَيَقُولُ: لَا يَا رَبِّ، فَيَقُولُ: بَلَى إِنَّ لَكَ عِنْدَنَا حَسَنَةً، فَإِنَّهُ لَا ظُلْمَ عَلَيْكَ الْيَوْمَ، فَتُخْرَجُ بِطَاقَةٌ فِيهَا: أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، فَيَقُولُ: احْضُرْ وَزْنَكَ، فَيَقُولُ: يَا رَبِّ مَا هَذِهِ الْبِطَاقَةُ مَعَ هَذِهِ السِّجِلَّاتِ؟ فَقَالَ: إِنَّكَ لَا تُظْلَمُ، قَالَ: فَتُوضَعُ السِّجِلَّاتُ فِي كِفَّةٍ، وَالْبِطَاقَةُ فِي كِفَّةٍ، فَطَاشَتِ السِّجِلَّاتُ، وَثَقُلَتِ الْبِطَاقَةُ، فَلَا يَثْقُلُ مَعَ اسْمِ اللهِ شَيْءٌ».

[صحيح] - [رواه الترمذي وابن ماجه] - [سنن الترمذي: 2639]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Amru ọmọ ‘Aas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ, O maa ṣí ìwé iṣẹ mọkandinlọgọrun-un fun un, ìwé kọ̀ọ̀kan gùn ni odiwọn ibi tí ojú bá le rína dé, lẹyin naa O maa sọ pé: Ǹjẹ́ nǹkan kan n bẹ nínú eyi ti o fẹ takò? Ǹjẹ́ àwọn malaika òǹkọ̀wé-iṣẹ́ ẹ̀dá ti wọn jẹ oluṣọ ṣe àbòsí rẹ bi? O maa sọ pé: Rara, Irẹ Olúwa mi, O maa sọ pé: Ǹjẹ́ o ni àwíjàre kankan bi? O maa sọ pé: Rárá, Irẹ Oluwa mi, O maa sọ pé: Ko ri bẹẹ, dájúdájú o ni iṣẹ rere kan ni ọdọ Wa; torí pé ko si àbòsí fun ẹ ni oni, wọn maa wa mu iwe pélébé kan jáde ti ohun ti o wa ninu rẹ jẹ: ASH’HADU AN LAA ILAAHA ILLALLOHU, WA ASH’HADU ANNA MUHAMMADAN ABDUHUU WA ROSUULUHUU, O maa sọ pé: Mu òṣùwọ̀n rẹ wá, o maa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, iwe pélébé wo ni o wa pẹ̀lú àwọn ìwé iṣẹ yii? O maa sọ pé: Wọn ko nii ṣe abosi fun ọ, o sọ pe: Wọn maa gbe àwọn ìwé iṣẹ naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n kan, wọn si maa fi iwe pélébé naa sórí abọ́ òṣùwọ̀n mii, ni àwọn iwe iṣẹ naa maa di ohun ti o fúyẹ́, ti iwe pélébé naa si maa wúwo, ko si nnkan kan ti o le wuwo ju orúkọ Ọlọhun lọ”.

[O ni alaafia] - [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2639]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun maa ṣẹsa arakunrin kan ninu ijọ rẹ lójú awọn ẹda ni ọjọ igbedide, wọn maa pe e lati ṣe ìṣirò iṣẹ fun un, O si maa fi iwe àkọsílẹ̀ mọkandinlọgọrun-un han an, àwọn naa ni awọn iwe awọn iṣẹ aburu rẹ ti o n ṣe ni aye, ati pe òró iwe àkọsílẹ̀ kọọkan gùn ni ìwọ̀n ibi tí irina ba dé, Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin naa pe: Njẹ waa tako nnkankan ninu nnkan ti wọn kọ sinu awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Njẹ awọn Mọlaika mi Olùṣọ́ Olukọwe ṣe abosi rẹ? Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Njẹ awijare n bẹ fun ẹ ninu nnkan ti o ti siwaju ninu awọn iṣẹ ni aye? Bóyá o jẹ igbagbe tabi àṣìṣe tabi aimọkan, Arakunrin naa maa sọ pé: Rara Oluwa mi, mi ko ni awijare kankan. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Bẹẹ kọ, dajudaju daadaa kan n bẹ fun ẹ lọdọ wa, ati pe ko si abosi kan fun ẹ lónìí. O sọ pe: Yoo mu kaadi kan jade ti wọn kọ sibẹ pé: Mo n jẹrii pe ko si ẹni ti ìjọsìn tọ si ni ododo afi Allahu, mo si n jẹrii pe Muhammad ẹrusin Ọlọhun ni ati Ojiṣẹ Rẹ. Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ fun arakunrin yii pé: Mú òṣùwọ̀n rẹ wa. Arakunrin naa maa sọ ni ẹni ti o n ṣe eemọ pé: Irẹ Oluwa mi! Ki ni òṣùwọ̀n kaadi yii já mọ́ ni ẹ̀gbẹ́ awọn iwe àkọsílẹ̀ yii? Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- maa sọ pé: Abosi ko lee ṣẹlẹ̀ si ẹ lailai. O sọ pe: Wọn yoo gbe awọn iwe àkọsílẹ̀ naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan, ati kaadi naa sinu abọ́ òṣùwọ̀n kan; bayii ni abọ́ òṣùwọ̀n ti awọn iwe àkọsílẹ̀ wa nibẹ maa di ohun ti o fuyẹ, ti abọ́ òṣùwọ̀n ti kaadi wa ninu rẹ maa tẹṣuwọn ti o maa wuwo, ni Ọlọhun ba maa fi ori jin in.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Titobi gbolohun imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo: Jijẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si ni ododo afi Allahu, ati wiwuwo rẹ ninu òṣùwọ̀n.
  2. Sisọ gbolohun: Laa ilaaha illallohu ko tó pẹlu ahọn nikan, bi ko ṣe pe nini imọ nípa ìtumọ̀ rẹ ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu nnkan ti o n bèèrè fun jẹ dandan.
  3. Imọkanga ati agbara imu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo jẹ okùnfà pípa awọn ẹṣẹ rẹ.
  4. Igbagbọ maa n ju ara wọn lọ pẹ̀lú bi ohun ti n bẹ ninu ọkan ba ṣe ju ara lọ nibi imọkanga, awọn kan ninu awọn eniyan a maa sọ gbolohun yii ṣùgbọ́n wọn maa fi iya jẹ wọn ni odiwọn awọn ẹṣẹ wọn.