+ -

عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنْ رَسُولِ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَمَّا خَلَقَ اللَّهُ الْجَنَّةَ وَالنَّارَ أَرْسَلَ جِبْرِيلَ عَلَيْهِ السَّلَامُ إِلَى الْجَنَّةِ، فَقَالَ: انْظُرْ إِلَيْهَا وَإِلَى مَا أَعْدَدْتُ لِأَهْلِهَا فِيهَا. فَنَظَرَ إِلَيْهَا فَرَجَعَ، فَقَالَ: وَعِزَّتِكَ لَا يَسْمَعُ بِهَا أَحَدٌ إِلَّا دَخَلَهَا. فَأَمَرَ بِهَا فَحُفَّتْ بِالْمَكَارِهِ، فَقَالَ: اذْهَبْ إِلَيْهَا فَانْظُرْ إِلَيْهَا وَإِلَى مَا أَعْدَدْتُ لِأَهْلِهَا فِيهَا. فَنَظَرَ إِلَيْهَا، فَإِذَا هِيَ قَدْ حُفَّتْ بِالْمَكَارِهِ، فَقَالَ: وَعِزَّتِكَ لَقَدْ خَشِيتُ أَنْ لَا يَدْخُلَهَا أَحَدٌ. قَالَ: اذْهَبْ فَانْظُرْ إِلَى النَّارِ وَإِلَى مَا أَعْدَدْتُ لِأَهْلِهَا فِيهَا. فَنَظَرَ إِلَيْهَا فَإِذَا هِيَ يَرْكَبُ بَعْضُهَا بَعْضًا، فَرَجَعَ فَقَالَ: وَعِزَّتِكَ لَا يَدْخُلُهَا أَحَدٌ. فَأَمَرَ بِهَا فَحُفَّتْ بِالشَّهَوَاتِ، فَقَالَ: ارْجِعْ فَانْظُرْ إِلَيْهَا. فَنَظَرَ إِلَيْهَا فَإِذَا هِيَ قَدْ حُفَّتْ بِالشَّهَوَاتِ، فَرَجَعَ وَقَالَ: وَعِزَّتِكَ لَقَدْ خَشِيتُ أَنْ لَا يَنْجُوَ مِنْهَا أَحَدٌ إِلَّا دَخَلَهَا».

[حسن] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي] - [سنن أبي داود: 4744]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla maa ba a- lọ sí alujanna, O wa sọ pé: Wò ó, ki o si wo ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fun awọn ọmọ alujanna ninu rẹ. Ni o ba wo o, o si ṣẹri pada, ni o wa sọ pe: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa gbọ nipa rẹ ti ko nii wọ̀ ọ́. Ni O ba pàṣẹ ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika rẹ, O wa sọ pé: Tún lọ sibẹ, ki o si wo o ati ohun ti Mo pèsè kalẹ̀ fún àwọn ọmọ alujanna nínú rẹ̀. Ni o wa wo o, o si ba a pe wọn ti fi àwọn ohun tí ẹ̀mí korira rọkirika rẹ, o wa sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ẹ̀rù n ba mi ki ẹni kankan ma wọ ibẹ̀. O sọ pé: Lọ wo ina ati ohun ti Mo pèsè kalẹ fun awọn ọmọ ina nínú ẹ. O wo inu rẹ, ni o wa ri i ti o n gun ara wọn, o ṣẹri pada, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, ko si ẹni kankan ti o maa wọ̀ ọ́. Ni O wa ni ki wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi maa n gbádùn rọkirika rẹ, o padà, o si sọ pé: Mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹni kankan má là kúrò nibẹ ayafi ki o wọ̀ ọ́”.

[O daa] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 4744]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju Ọlọhun, nigba ti O da alujanna ati ina, O sọ fun Jibril- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- pé: Lọ si alujanna ki o si wo o, bayii ni o ṣe lọ, o si wo o, lẹyin naa o ṣẹri pada, Jubril si sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa rẹ ati nipa nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu idẹra ati awọn oore afi ko fẹ lati wọ ọ, ki o si maa ṣe iṣẹ́ nitori rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun wa fi awọn nnkan ti ẹmi korira ati awọn nǹkan ti ó le rọkirika alujanna bii ṣíṣe awọn nnkan ti wọn pa wa láṣẹ ati jijina si awọn nnkan ti wọn kọ̀; o wa jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ wọ ọ lati re kọja awọn nnkan ti ẹmi korira yẹn. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- sọ pé: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo alujanna, lẹyin igba ti O rọkirika rẹ pẹlu awọn nnkan ti ènìyàn korira, O si lọ wo o, lẹyin naa o sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, mo n paya ki ẹnikẹni ma wọ ọ pẹlu okunfa awọn ilekoko ati awọn wahala ti wọn wa ni oju ọna rẹ. Nígbà ti Ọlọhun da ina, O sọ pe: Irẹ Jibril! Lọ ki o lọ wo o, o si lọ wo o, Lẹyin naa ni o dé, Jibril wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa iya ati awọn wahala ati ìfìyàjẹ ti o wa nínú rẹ̀ afi ki o korira lati wọ ọ ki o sì jina si awọn okunfa rẹ. Lẹyin naa Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- fi àwọn adùn rọkirika ina, O si ṣe wọn ni oju ọna lọ si ibẹ, lẹyin naa, O sọ pe: Irẹ Jibril, lọ ki o si wo o, Jibril si lọ o si wo o, lẹyin naa o de, o si sọ pe: Irẹ Oluwa mi, mo fi agbara Rẹ bura, dajudaju mo paya ẹru si ba mi pe ki ẹni kankan ma la kuro nibẹ; fun nnkan ti o rọkirika rẹ ninu awọn adun.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Nini igbagbọ pe alujanna ati ina n bẹ báyìí.
  2. Jijẹ dandan nini igbagbọ ninu kọ̀kọ̀ ati gbogbo nnkan ti o wa lati ọdọ Ọlọhun ati lati ọdọ Ojiṣẹ Rẹ (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).
  3. Pataki ṣíṣe suuru lori awọn nnkan ti ènìyàn korira; nitori pe àwọn ni oju ọna ti o de alujanna.
  4. Pataki jijina si awọn nnkan eewọ; nitori pe àwọn ni oju ọna ti o de ina.
  5. O ṣe alujanna ni nnkan ti wọn fi àwọn nǹkan ti ẹmi korira rọkirika, O si ṣe ina ni nǹkan ti wọn fi àwọn adùn rọkirika, oun ni nǹkan ti ìdánwò isẹmi ayé n béèrè fun.
  6. Oju ọna alujanna ṣoro o si le, o si bukaata si ṣíṣe suuru ati atẹmọra pẹlu igbagbọ, ati pe oju ọna ina kun fun adun ni aye.