عن سهل بن سعد رضي الله عنه عن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ يَضْمَنْ لِي مَا بَيْنَ لَحْيَيْهِ وَمَا بَيْنَ رِجْلَيْهِ أَضْمَنْ لَهُ الْجَنَّةَ».
[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 6474]
المزيــد ...
Lati ọdọ Sahl ọmọ Sahd - ki Ọlọhun yọnu si i - ó gba a wa lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – pé ó sọ pé:
"Ẹnikẹ́ni tí ó bá fi dámilójú pé oun yóò ṣọ́ nkan tí n bẹ láàrín eegun ẹnu rẹ méjèèjì àti nkan tí n bẹ láàrín ẹsẹ̀ rẹ méjèèjì, èmi yóò fi dá a lójú pé yoo wọ Alujanna".
[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6474]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọrọ nipa awọn nkan meji tó ṣe pé tí Musulumi bá dúnní mọ́ wọn, dajudaju yóò wọ Alujanna.
Ikinni: Ṣíṣọ́ ẹnu kuro nibi sísọ nkan tí ó maa fa ibinu Ọlọhun Ọba,
Èkejì: Ṣíṣọ́ abẹ́ kuro nibi ìṣekúṣe;
nítorí pé awọn oríkèé ara meji wọnyi, ẹ̀ṣẹ̀ máa n waye latara wọn lọpọlọpọ ìgbà.