عَنْ أَبِي بَكْرٍ الصِّدِّيقِ رضي الله عنه أَنَّهُ قَالَ: أَيُّهَا النَّاسُ، إِنَّكُمْ تَقْرَؤُونَ هَذِهِ الآيَةَ: {يَا أَيُّهَا الَّذِينَ آمَنُوا عَلَيْكُمْ أَنْفُسَكُمْ لاَ يَضُرُّكُمْ مَنْ ضَلَّ إِذَا اهْتَدَيْتُمْ}، وَإِنِّي سَمِعْتُ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«إِنَّ النَّاسَ إِذَا رَأَوْا الظَّالِمَ فَلَمْ يَأْخُذُوا عَلَى يَدَيْهِ أَوْشَكَ أَنْ يَعُمَّهُمُ اللَّهُ بِعِقَابٍ مِنْهُ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والترمذي والنسائي في الكبرى وابن ماجه وأحمد] - [سنن الترمذي: 2168]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Bakr- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo pe ẹyin eniyan, ẹ maa n ka aayah yìí: (Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na), mo si gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
"Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi, ti wọn ko si gba a mu ni ọwọ rẹ mejeeji, o sunmọ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari wọn".
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ, ati Ibnu Maajah ati Ahmad] - [Sunanu ti Tirmidhiy - 2168]
Abu Bakr As-Sideeq- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan a maa ka aayah yìí:
(Ẹ̀yin tí ẹ gbàgbọ́ ní òdodo, ẹ̀mí ara yín dọwọ́ yín. Ẹni tí ó ti ṣìnà kò lè kó ìnira ba yín nígbà tí ẹ bá ti mọ̀na)(Al-Maa'ida: 105).
Ti wọn maa wa gbọye ninu rẹ pe dajudaju igbiyanju jẹ dandan lori ọmọniyan lori titun ara rẹ ṣe nikan, ati pe ìṣìnà ẹni ti o ṣina ko nii ko inira ba a lẹyin ìyẹn, ati pe wọn ko wa lati ọdọ wọn pipáṣẹ daadaa ati kikọ iwa ibajẹ!
ni o wa fi mọ wọn pe ko ri bayẹn, pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa a- n sọ pe: Dajudaju awọn eniyan ti wọn ba ti ri alabosi ti wọn ko si kọ fun un kuro nibi abosi ṣíṣe rẹ, ti agbara lori kikọ fun un si n bẹ lọdọ wọn, ó maa ku díẹ̀ ki Ọlọhun fi iya kan lati ọdọ Rẹ kari gbogbo wọn, ẹni ti o n ṣe ibajẹ ati ẹni ti o n dakẹ nipa rẹ.