عن جابر بن عبد الله رضي الله عنهما قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ لَقِيَ اللهَ لَا يُشْرِكُ بِهِ شَيْئًا دَخَلَ الْجَنَّةَ، وَمَنْ لَقِيَهُ يُشْرِكُ بِهِ دَخَلَ النَّارَ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 93]
المزيــد ...
Lati ọdọ Jabir ọmọ Abdullah - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Mo gbọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti n sọ pe:
"Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 93]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye pé ẹnikẹni tí ó bá kú, tí kò mu orogun kankan pẹlu Ọlọhun, Alujanna ni ibupadasi rẹ̀ kódà bí wọ́n bá jẹ ẹ niya nitori apakan ninu awọn ẹṣẹ rẹ̀, ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba ku, ni ẹniti n mu orogun pẹlu Ọlọhun, onitọhun yoo wọ inu Ina gbere.