عَنْ عَبْدِ اللهِ بنِ مَسْعُودٍ رضي الله عنه قال:
قَالَ النَّبِيُّ صلى الله عليه وسلم كَلِمَةً وَقُلْتُ أُخْرَى، قَالَ النَّبِيُّ صلى الله عليه وسلم: «مَنْ مَاتَ وَهُوَ يَدْعُو مِنْ دُونِ اللهِ نِدًّا دَخَلَ النَّارَ» وَقُلْتُ أَنَا: مَنْ مَاتَ وَهُوَ لَا يَدْعُو لِلهِ نِدًّا دَخَلَ الْجَنَّةَ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 4497]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé:
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ ọrọ kan, emi naa sọ omiran, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina" emi naa sọ pe: Ẹni ti o ba ku, ti ko si kii n pe akẹgbẹ kan mọ Ọlọhun, o maa wọ alujanna.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4497]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ fun wa pe dajudaju ẹni ti o ba yi nnkan kan ninu nnkan ti o jẹ dandan lati jẹ ti Ọlọhun fun ẹni ti o yàtọ̀ si I, gẹgẹ bii pipe ẹni ti o yàtọ̀ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- tabi wiwa iranlọwọ lọ sọdọ ẹni ti o yàtọ̀ si I, ti o si ku lori rẹ, dajudaju o maa wa ninu awọn ara ina. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ṣalekun pe dajudaju ẹni ti o ba ku ti ko da nnkan kan pọ mọ Ọlọhun, dajudaju ibuṣẹripadasi rẹ ni alujanna.