عن عبد الله بن مسعود قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«هَلَكَ الْمُتَنَطِّعُون» قالها ثلاثًا.

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2670]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abdullah ọmọ Mas'ud ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pé:
"Awọn alakatakiti ti parun " ó sọ bẹẹ ni ẹẹmẹta.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2670]

Àlàyé

Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n fún wa niroo nipa ìpòfo ati ipadanu awọn onilekoko - laisi ìmọ̀nà ati ìmọ̀ - ninu ẹsin ati igbesi aye wọn, ati ninu awọn ọrọ wọn ati awọn iṣẹ wọn, awọn tí wọ́n máa ń tayọ aala ofin sharia tí Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - mú wá fún wa.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Eewọ ni ilekoko ati tipátipá ninu gbogbo nkan, kí a sì gbiyanju lati jina si mejeeji ninu ohun gbogbo; paapaa julọ ninu awọn ijọsin wa ati igbe-titobi fun awọn ẹnirere.
  2. Wíwá lati ṣe ijọsin ati awọn ohun miiran ní pípé jẹ́ nkan dáadáa; ó sì ni lati jẹ́ pẹlu titẹle ofin sharia.
  3. Wọ́n fẹ́ kí a maa tẹnumọ́ ọ̀rọ̀ pataki, nitori pé Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tún gbolohun yii sọ ni ẹẹmẹta.
  4. Ìrọ̀rùn ẹ̀sìn Islam ati àilekoko rẹ̀.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)