عَن عُمَرَ بنِ الخَطَّابِ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قال: سَمِعْتُ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَقُولُ:
«لَا تُطْرُونِي كَمَا أَطْرَتِ النَّصَارَى ابْنَ مَرْيَمَ؛ فَإِنَّمَا أَنَا عَبْدُهُ، فَقُولُوا: عَبْدُ اللهِ وَرَسُولُهُ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 3445]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umar ọmọ Al-Khattab - ki Ọlọhun yọnu si i - ó sọ pé: Mo gbọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - tí ń ṣo pé:
"Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀".

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3445]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fun wa kuro nibi ìyinnijù ati ikọja aala ofin sharia nibi yiyin-in ati riroyin rẹ̀ pẹlu awọn iroyin Ọlọhun Ọba ati awọn iṣẹ tó jẹ́ ti Ọlọhun nikan ṣoṣo, tabi kí a sọ pé Anabi ní imọ kọ̀kọ̀, tabi ki a maa pe e papọ mọ Ọlọhun, gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe ṣe pẹlu Isa ọmọ Maria - ki alaafia Ọlọhun maa ba a. Lẹyin naa, Anabi ṣalaye pé ẹru kan ninu awọn ẹru Ọlọhun ni oun, ó sì paṣẹ pé ki a maa sọ nipa oun bayii pé: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Iṣọnilara kuro nibi titayọ aala ofin sharia nibi ẹyìn; nitori pe ó máa n ja si ẹbọ ni.
  2. Ohun ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kilọ fun wa nipa rẹ̀, ó ti ṣẹlẹ ninu ijọ yii, nitori awọn ẹgbẹ kan ti tayọ aala lara Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - awọn ẹgbẹ kan sì tayọ aala lara awọn ara ile Anabi, awọn ẹgbẹ kan tún tayọ aala lara awọn wòlíì Ọlọhun, gbogbo wọn bá kó sinu ẹbọ.
  3. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ẹru Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ẹru ti Allah ń rè ni oun, nitori naa kò lẹtọọ ki a dari nkankan ninu awọn ìròyìn ẹ̀ṣà Oluwa si ọdọ rẹ̀.
  4. Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - royin ara rẹ̀ pé ojiṣẹ Ọlọhun ni oun; nitori kí ó lè fi hàn pé dajudaju ojiṣẹ kan lati ọdọ Ọlọhun ni oun, nitori naa ọranyan ni ki a pe e lódodo ki a si tẹle e.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)