____
[] - []
المزيــد ...
Lati ọdọ baba Hamur - wàn tilẹ sọ pé Bàbá Hamrata ni - , òun ni Sufyan ọmọ Abdullahi kí Ọlọhun yọnu sí o sọ pé:
Mo sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [الأربعون النووية - 21]
Saabe Sufyan ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere lati kọ oun ni ọrọ kan ti o ko awọn ìtumọ̀ Isilaamu sinu, ti oun maa dirọ mọ ọn, ti oun ko si nii bi ẹni ti o yàtọ̀ si i leere nipa rẹ? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun un pé: sọ pe Mo mu Ọlọhun lọkan, mo si gbagbọ pe Oluwa mi ni ati Ọlọhun mi ati Aṣẹ̀dá mi ati Ẹni ti maa maa jọsin fun lododo ti ko si orogun fun Un, Lẹyin naa, yoo tẹ fun itẹle Ọlọhun pẹlu ṣíṣe awọn ọran-anyan Ọlọhun ati gbigbe awọn eewọ Ọlọhun ju silẹ ti yoo si maa tẹsiwaju lori rẹ.