Ìsọ̀rí:
+ -

عَنْ أَبِي رُقَيَّةَ تَمِيمِ بْنِ أَوْسٍ الدَّارِيِّ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«الدِّينُ النَّصِيحَةُ» قُلْنَا: لِمَنْ؟ قَالَ: «لِلهِ وَلِكِتَابِهِ وَلِرَسُولِهِ وَلِأَئِمَّةِ الْمُسْلِمِينَ وَعَامَّتِهِمْ».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [الأربعون النووية: 7]
المزيــد ...

Lati ọdọ baba Ruqọyyah Tameem ọmọ Aosi Addariyy kí Ọlọhun yọnu sí dájú dájú anọbi kí Ikẹ Ọlọhun àti ọlá Rẹ má bà sọ pé:
“Ẹsin ìmọ̀ràn ni”, a sọ pé: Fún tani? O sọ pe: “Fún Ọlọhun, ati fun tira Rẹ̀, ati fun ojiṣẹ Rẹ, ati fun awọn aṣiwaju Mùsùlùmí ati apapọ wọn”.

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [الأربعون النووية - 7]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹsin duro lori imọkanga ati ododo, titi ti eeyan fi maa pé e gẹ́gẹ́ bi Ọlọhun ṣe ṣe e ni dandan, ni pípé láìsí ikudiẹ-kaato nibẹ tabi irẹjẹ. Wọn wa sọ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Ìmọ̀ràn fun tani? O sọ pe: Akọkọ: mímọ fun Ọlọhun ti ọla Rẹ ga: Pẹ̀lú mimọ iṣẹ kangá fun Un, ati ki èèyàn ma da orogun pọ̀ mọ́ Ọn, ki a si gbagbọ ninu ijẹ Oluwa Rẹ, ati ìní-ẹ̀tọ́ si ìjọsìn Rẹ, ati awọn orúkọ Rẹ ati awọn ìròyìn Rẹ, ati gbigbe ọ̀rọ̀ Rẹ tobi, ati ipepe lọ sibi ìní ìgbàgbọ́ si I. Ẹkeji: Ṣíṣe mimọ sí ọrọ rẹ òun náà ni Al-qur'aani alapọnle: pẹlu pé kí a ní adisọkan pé ọrọ ọrọ rẹ ni , àti pe oun ni igbẹyin awan tira rẹ, àti pe oun ni o se iparẹ gbgbo awan ìlànà òfin tí o tí wa síwájú re6, kí o sí máa gbé tóbi, kí o sí máa kàà bode yẹ koro ka , kí o sí máa lo èyí tí ìdájọ rẹ fojú hàn, kí o sí gbafa fún èyí tí o jọra wàn tàbí èyí tí o ru'ju nínú rẹ, kí a sí jìnà sí ituku awan tí wan tú ni itukutu, kí a sí máa ni iwoye sí awan ìkìlọ tàbí isiti rẹ, kí a sí má tán awan imọ rẹ ka , kí a sí pepe sí ará rẹ. Ìkẹta: Ìmọ̀ràn fun ojiṣẹ Rẹ tii ṣe Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Pẹ̀lú ki a ni adisọkan pe oun ni igbẹyin àwọn ojiṣẹ, ki a si gba a lododo nibi nǹkan ti o mu wa, ki a si tẹle àṣẹ rẹ, ki a si jinna si ohun ti o bá kọ̀. Ki a si ma jọ́sìn fun Ọlọhun àyàfi pẹ̀lú nǹkan ti o mu wa, ki a si maa gbe iwọ̀ rẹ tobi, ki a si maa pọn ọn le, ki a si maa tan ipepe rẹ ká, ki a si maa fọn ofin rẹ ka, ki a si maa tako àwọn ẹ̀sùn ti wọn ba fi kan an. Ikẹrin: Ìmọ̀ràn fun awọn aṣiwaju àwọn mùsùlùmí: Pẹ̀lú riran wọn lọ́wọ́ lórí òdodo, ki eeyan ma si du àlámọ̀rí naa mọ́ wọn lọ́wọ́, ki èèyàn si maa tẹti ki èèyàn si maa tẹle àṣẹ wọn nibi itẹle ti Ọlọhun. Ikarun-un: Ìmọ̀ràn fun awọn Mùsùlùmí: Pẹ̀lú ṣíṣe dáadáa si wọn ati pípè wọn, ati ki èèyàn má fi suta kan wọn, ati inifẹẹ oore fun wọn, ati kikun wọn lọ́wọ́ lori dáadáa ati ìpayà.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Pipaṣẹ ìmọ̀ràn fun gbogbo èèyàn.
  2. Titobi ipò imọran ninu ẹsin.
  3. Ẹ̀sìn kó àwọn adisọkan ati awọn gbólóhùn ati awọn iṣẹ sínú.
  4. Lára imọran naa ni fifọ ẹmi mọ́ kuro nibi irẹjẹ fun ẹni ti a gba ni imọran ati gbigbero oore fun un.
  5. Ìkọ́ni-daadaa Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- níbi ti o ti dárúkọ nǹkan ni ṣókí, lẹ́yìn naa ni o wa sọ ọ ni ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
  6. Bibẹrẹ pẹlu bi nǹkan ba ṣe pàtàkì jù tó, nibi ti Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìmọ̀ràn fun Ọlọhun, lẹyin naa fun tira Rẹ̀, lẹ́yìn náà fun ojiṣẹ Rẹ̀- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lẹ́yìn náà fun awọn aṣiwaju àwọn Mùsùlùmí, lẹyin naa fun gbogbo Musulumi ni apapọ.
Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية الخميرية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Àwọn ìsọ̀rí
Àlékún