+ -

عَنِ ابْنِ مَسْعُودٍ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«سَتَكُونُ أَثَرَةٌ وَأُمُورٌ تُنْكِرُونَهَا» قَالُوا: يَا رَسُولَ اللَّهِ فَمَا تَأْمُرُنَا؟ قَالَ: «تُؤَدُّونَ الحَقَّ الَّذِي عَلَيْكُمْ، وَتَسْأَلُونَ اللَّهَ الَّذِي لَكُمْ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 3603]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Imọtaraẹni-nikan maa wa ati awọn àlámọ̀rí kan ti ẹ maa takò wọn" wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ki ni nnkan ti o maa pa wa láṣẹ? O sọ pe: "Ẹ maa pe ẹtọ ti o jẹ dandan fun yin, ẹ si maa beere lọwọ Ọlọhun nnkan ti o jẹ ti yin".

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 3603]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn adari kan maa jẹ lori awọn Musulumi ti wọn ma maa wuwa imọtaraẹninikan pẹlu awọn dukia Musulumi ati eyi ti o yàtọ̀ si i ninu awọn àlámọ̀rí aye, ti wọn ma maa na an gẹgẹ bi wọn ṣe fẹ, ti wọn ma maa kọ fun awọn Musulumi nibi ẹtọ wọn nibẹ. O si maa waye lati ọwọ wọn, awọn àlámọ̀rí kan ti wọn kọ ninu ẹsin. Awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- beere pé: Ki ni awọn maa ṣe nibi isẹsi yẹn? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn pe didana owo wọn ko lee kọ fun yin lati jẹ ki ẹ kọ nnkan ti o jẹ dandan fun yin si wọn ninu gbigbọ ati itẹle, bi ko ṣe pe ki ẹ ṣe suuru ki ẹ si gbọ́ ki ẹ si tẹle,ẹ ko si gbọdọ fa àlámọ̀rí mọ wọn lọwọ, ki ẹ si beere ẹtọ ti o jẹ ti yin lọdọ Ọlọhun, ati pe ki O tun wọn ṣe, ki O si ti aburu wọn ati abosi wọn lọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Hadiisi naa wa ninu awọn itọka ijẹ anabi rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nigba ti o sọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu ìjọ rẹ ti o si ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi o ṣe sọ.
  2. Ṣíṣe lẹtọọ sisọ fun ẹni ti adanwo fẹ kan nípa nnkan ti wọn maa mu ṣẹlẹ̀ si i ninu àdánwò; lati pese ara rẹ kalẹ, ti o ba ti wa de ba a yoo jẹ onisuuru ti o maa reti ẹsan lati ọdọ Ọlọhun.
  3. Idirọmọ Kuraani ati sunnah maa n mu ni jade kuro nibi awọn fitina ati iyapa.
  4. Ṣiṣenilojukokoro lori gbigbọ ati itẹle fun awọn adari pẹlu daadaa, ati aima jade le wọn lori, ko da ki abosi ṣẹlẹ̀ lati ọdọ wọn.
  5. Lilo ọgbọ́n ati itẹle sunnah ni asiko awọn fitina.
  6. O jẹ dandan fun ọmọniyan lati ṣe ẹtọ ti o jẹ dandan fun un, ko da ki nnkan kan ṣẹlẹ̀ si i ninu abosi.
  7. Ẹri n bẹ nibẹ lori ipilẹ: Ṣíṣe ẹsa eyi ti o rọrun julọ ninu aburu meji tabi eyi ti o fuyẹ julọ ninu inira meji.