عن عُبَادَةَ بن الصَّامتِ رضي الله عنه قال:
بَايَعْنَا رسولَ اللهِ صلى الله عليه وسلم على السَّمْعِ وَالطَّاعَةِ فِي الْعُسْرِ وَالْيُسْرِ، وَالْمَنْشَطِ وَالْمَكْرَهِ، وعلى أَثَرَةٍ علينا، وعلى أَلَّا نُنَازِعَ الْأَمْرَ أهلَه، وعلى أَنْ نَقُولَ بِالْحَقِّ أينما كُنَّا، لا نَخَافُ في الله لَوْمَةَ لَائِمٍ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 1709]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Ubaadatu ọmọ As-Soomit- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
A ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori gbigbọ ati itẹle nigba ilekoko ati irọrun, ati nibi nnkan ti a fẹ ati nnkan ti a kọ, ati lori iwa imọtaraẹni nikan, ati pe lori pe a ko gbọdọ fa alamọri mọ awọn ti wọn ni in lọwọ, ati lori pe ki a maa sọrọ pẹlu ododo ni ayekaye ti a ba wa, a ko nii bẹru eebu buni buni kan ni oju ọna Ọlọhun.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 1709]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gba adehun ati majẹmu lọwọ awọn sahaabe nibi itẹle fun awọn olori ati awọn adari nigba idẹkun ati ilekoko ati nigba ọrọ ati oṣi, boya awọn aṣẹ wọn wa latara nnkan ti ẹ̀mí fẹ tabi ti o kọ, koda ti awọn adari ba ṣe imọtaraẹni nikan pẹlu owo gbogboogbo tabi awọn ipo tabi nnkan ti o yatọ si wọn, dajudaju gbigbọ ati itẹle jẹ dandan fun wọn pẹlu daadaa, ati pe wọn ko gbọdọ jade le wọn lori nitori pe wahala ati ibajẹ ti o n bẹ nibi biba wọn ja tobi o si le koko ju ibajẹ ti o n waye pẹlu ṣíṣe abosi wọn lọ, ati pe ninu nnkan ti wọn ṣadehun rẹ fun un ni ki wọn maa sọ ododo ni ayekaye ti wọn wa ti wọn n ṣe imọkanga nibi ìyẹn fun Ọlọhun ti wọn ko si nii maa bẹru ẹni ti o ba n bu wọn.