عن عرفجة رضي الله عنه قال: سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَنْ أَتَاكُمْ وَأَمْرُكُمْ جَمِيعٌ عَلَى رَجُلٍ وَاحِدٍ، يُرِيدُ أَنْ يَشُقَّ عَصَاكُمْ، أَوْ يُفَرِّقَ جَمَاعَتَكُمْ، فَاقْتُلُوهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1852]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Arfaja – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe:
«Ẹni ti o ba wa ba yin nigba ti ọrọ yin papọ lori arakunrin kan, ti o wa n gbero láti ya yin, tabi lati pin akojọpọ yin, ki ẹ yaa pa a».
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1852]
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n ṣe alaye wipe dajudaju ti awọn Musulumi ba kojọ lori olori kan, ati akojọpọ kan, lẹyin naa ni ẹni ti o fẹ ba a du ipo aṣẹ wa de, tabi ti o gbero lati pin awọn Musulumi si ijọ ti o pọ ju ẹyọkan lọ, o jẹ dandan fun wọn lati kọ fun un ati lati ba a ja; lati fi ti aburu rẹ danu ati lati fi da aabo bo ẹjẹ awọn Musulumi.