+ -

عَنْ أُمِّ سَلَمَةَ أُمِّ المُؤمنين رضي الله عنها: أَنَّ رَسُولَ اللهِ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«سَتَكُونُ أُمَرَاءُ فَتَعْرِفُونَ وَتُنْكِرُونَ، فَمَنْ عَرَفَ بَرِئَ، وَمَنْ أَنْكَرَ سَلِمَ، وَلَكِنْ مَنْ رَضِيَ وَتَابَعَ» قَالُوا: أَفَلَا نُقَاتِلُهُمْ؟ قَالَ: «لَا، مَا صَلَّوْا».

[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 1854]
المزيــد ...

Lati ọdọ Umu salamah iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe:
"Awọn adari kan maa jẹ, ẹ maa mọ ẹ si maa ṣe atako, ẹni ti o ba mọ, o ti bọ, ẹni ti o ba ṣe atako, o ti la, sugbọn ẹni ti o ba yọnu ti o si tẹle" wọn sọ pe: Njẹ a ko nii ba wọn ja? O sọ pe: "Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n kirun".

[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 1854]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe awọn olori kan maa jẹ lé wa lori, a maa mọ awọn kan ninu awọn iṣẹ wọn; nitori pe wọn ba nnkan ti wọn mọ ninu Sharia mu, a si maa tako awọn kan ninu wọn; nitori wọn yapa ìyẹn, Ẹni ti o ba korira ibajẹ pẹlu ọkan rẹ, ti ko kapa lori atako; o ti bọ kuro ninu ẹṣẹ ati ṣọbẹ-selu, Ẹni ti o ba kapa lori atako pẹlu ọwọ tabi ahọn, ti o wa tako ìyẹn fun wọn o ti la kuro nibi ẹṣẹ ati kikopa nibẹ, Ṣugbọn ẹni ti o ba yọnu si iṣe wọn ti o si tẹle wọn lori rẹ, o maa parun gẹgẹ bi wọn ṣe parun.
Lẹyin naa wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pe: Njẹ a ko nii ba awọn adari ti wọn ṣe pe eyi ni iroyin wọn ja? O wa kọ fun wọn kuro nibẹ, o wa sọ pe: Rara, lópin ìgbà tí wọ́n ba ṣi n gbé ìrun duro láàárín yin.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف Ti ede Azerbaijan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ninu awọn itọka ìjẹ́ anabi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni sisọ nnkan ti o maa ṣẹlẹ̀ ninu awọn kọ̀kọ̀ ati ṣiṣẹlẹ rẹ bi o ṣe sọ.
  2. Iyọnu si ibajẹ ko lẹtọọ tabi kikopa nibẹ, titako o si jẹ dandan.
  3. Ti awọn adari ba da nnkan ti o tako Sharia silẹ, itẹle wọn nibi ìyẹn ko lẹtọọ.
  4. Ailẹtọọ jijade si awọn adari Musulumi; nitori nnkan ti o wa ninu ìyẹn ninu ibajẹ ati ita ẹjẹ silẹ ati lílọ ifọkanbalẹ, itẹmọra ibajẹ awọn adari ẹlẹṣẹ, ati ṣíṣe suuru lori suta wọn rọrun ju ìyẹn lọ.
  5. Irun, ọrọ rẹ tobi, oun ni iyatọ laaarin aigbagbọ ati Isilaamu.