عَنْ عَائِشَةَ أُمِّ المُؤمنينَ رضي الله عنها قَالَتْ:
كُنْتُ أَغْتَسِلُ أَنَا وَالنَّبِيُّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ مِنْ إِنَاءٍ وَاحِدٍ كِلاَنَا جُنُبٌ، وَكَانَ يَأْمُرُنِي، فَأَتَّزِرُ، فَيُبَاشِرُنِي وَأَنَا حَائِضٌ، وَكَانَ يُخْرِجُ رَأْسَهُ إِلَيَّ وَهُوَ مُعْتَكِفٌ فَأَغْسِلُهُ وَأَنَا حَائِضٌ.
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 299]
المزيــد ...
Lati ọdọ 'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo maa n wẹ emi ati Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa ti awa mejeeji si jẹ ẹni ti o ni janaba lara, o maa n pa mi láṣẹ, ti maa si ro iro, ti o si maa n sunmọ mi ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu, o maa n yọ ori rẹ jade si mi ti o si n ṣe ittikaaf, ti maa si fọ̀ ọ́ ti mo si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 299]
'Aaisha iya awọn olugbagbọ- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ nipa apakan ninu awọn iṣesi rẹ ti o jẹ ẹsa pẹlu rẹ (Anabi) - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ninu rẹ ni pe: O maa n wẹ latara janaba pẹlu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu igba kan naa, ti awọn mejeeji si maa n bu omi ninu rẹ papọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sunmọ ọn ti o si jẹ ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu, ó maa pa a láṣẹ lati bo ara rẹ lati idodo de orunkun, ti o si maa fi ara rò ó laisi ibalopọ. Ati pe Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ṣe itikaaf ninu mọsalasi, yoo si gbe ori rẹ jade si 'Aaisha yio si wẹ ẹ ti o si wa ninu ile rẹ ni ẹni ti o n ṣe nnkan oṣu.