عن مَعقِلِ بن يَسار المُزَنِيّ رضي الله عنه قال: إني سمعت رسول الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«مَا مِنْ عَبْدٍ يَسْتَرْعِيهِ اللهُ رَعِيَّةً، يَمُوتُ يَوْمَ يَمُوتُ وَهُوَ غَاشٌّ لِرَعِيَّتِهِ، إِلَّا حَرَّمَ اللهُ عَلَيْهِ الْجَنَّةَ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 142]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Mah’qil ọmọ Yasaar Al-Muzaniy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pé:
“Ko si ẹrú kan ti Ọlọhun fi ṣe alaṣẹ lori awọn kan, ki o wa kú ni ọjọ́ ti o maa kú ti o si n tan àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ jẹ, àfi ki Ọlọhun ṣe alujanna ni eewọ fun un”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 142]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni kọọkan ti Ọlọhun ba fi ṣe olori fun awọn èèyàn, boya o jẹ àṣẹ ti gbogbogboo ni gẹgẹ bii alaṣẹ ìlú, tàbí àṣẹ ti kii ṣe ti gbogbogboo, gẹgẹ bii ọkùnrin ninu ile rẹ, ati obinrin ninu ile rẹ, ti o wa ṣe ohun ti o kù díẹ̀ káàtó nibi ẹ̀tọ́ àwọn ti n bẹ ni abẹ rẹ, o tun rẹ́ wọn jẹ, ko si gba wọn ni imọran, o wa fi iwọ̀ wọn ti ẹsin ati ayé ráre, o ti ni ẹ̀tọ́ si ìjìyà ti o le koko yìí.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Àdéhùn ìjìyà yii kii ṣe ti imaamu agba nìkan ati àwọn aṣojú rẹ, bi ko ṣe pe o kari gbogbo ẹni tí Ọlọhun ba ni ki o maa darí àwọn ti wọn wa ni abẹ rẹ.
  2. Ohun ti o jẹ dandan fun ẹni ti Ọlọhun ba ni ki o jẹ alaṣẹ fun nǹkan kan ninu àlámọ̀rí àwọn Musulumi ni ki o gba wọn ni ìmọ̀ràn, ki o si gbìyànjú láti pe agbafipamọ, ki o si ṣọ́ra fun ìjàǹbá.
  3. Titobi ojúṣe gbogbo ẹni tí o ba jẹ alaṣẹ gbogbogboo tabi ti ara ẹni, o tobi ni tabi o kere.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)