عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صلى الله عليه وسلم قَالَ:
«إِيَّاكُمْ وَالظَّنَّ؛ فَإِنَّ الظَّنَّ أَكْذَبُ الْحَدِيثِ، وَلَا تَحَسَّسُوا، وَلَا تَجَسَّسُوا، وَلَا تَحَاسَدُوا، وَلَا تَدَابَرُوا، وَلَا تَبَاغَضُوا، وَكُونُوا عِبَادَ اللهِ إِخْوَانًا».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6064]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
"Ẹ sọra fun aba dida; nitori pe aba dida jẹ eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ, ẹ ma ṣe maa ọ̀nà láti tu ihoho ara yin sita, ki ẹ si ma maa tọpinpin ara yin, ki ẹ si ma maa ṣe keeta ara yín, ki ẹ si ma maa kọ ẹyin si ara yin, ki ẹ si ma maa korira ara yín, ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6064]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n kọ o si n kilọ kuro nibi awọn kan ninu nnkan ti o le bi opinya ati ọta laaarin awọn Musulumi, Ninu ìyẹn ni:
(Az zonnu) oun ni ikẹfin ti o maa n ṣẹlẹ̀ ninu ọkan laini ẹri; o si ṣàlàyé pe o wa ninu eyi ti o jẹ irọ julọ ninu ọrọ.
Ati kuro nibi (At tahassus): Oun ni wiwadii nipa awọn ihoho awọn eniyan pẹlu oju tabi etí.
Ati (At-tajassus): Oun ni wiwadii nipa nnkan ti o pamọ ninu awọn alamọri, ibi tí wọ́n ti maa n sọ ìyẹn ju ni nibi aburú.
Ati kuro nibi: (Al hasad) oun ni ikorira ṣiṣẹlẹ idẹra fun awọn ẹlomiran.
Ati kuro nibi (At tadaabur) ki awọn kan ninu wọn maa gbúnrí kúrò lọ́dọ̀ awọn kan, ko nii salamọ, ko si nii ṣe abẹwo ọmọ-iya rẹ ti o jẹ Mùsùlùmí,
Ati kuro nibi: (At tabaagud) ati ikorira ati jíjìnnà-sini, gẹgẹ bii fifi suta kan awọn ẹlomiran, ati lile oju ati aima pade ara ẹni dáadáa.
Lẹyin naa, o sọ gbolohun ṣókí kan ti o ko nǹkan ti o pọ sínú ti o maa tun awọn isẹsi awọn Musulumi ṣe pẹlu ara wọn: (ki ẹ jẹ ẹru Ọlọhun ni ti ọmọ iya) Ati pe ìjẹ́ ọmọ iya jẹ asopọ kan ti awọn ajọṣepọ laaarin awọn eniyan fi maa n lẹ̀ pọ̀, ti o maa n lekun ifẹ ati irẹpọ láàárín wọn.