عن جابر بن عبد الله رضي الله عنهما عن النبي صلى الله عليه وسلم قال:
«كُلُّ مَعْرُوفٍ صَدَقَةٌ».

[صحيح] - [رواه البخاري من حديث جابر، ورواه مسلم من حديث حذيفة] - [صحيح البخاري: 6021]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe:
“Gbogbo dáadáa sàárà ni”.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa ninu hadiisi Jaabir, Muslim gba a wa nínú hadiisi Huzaifah] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6021]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe gbogbo dáadáa ati àǹfààní fun ẹlòmíràn, bóyá ọrọ ni tabi iṣẹ, o maa jẹ sàárà, ẹ̀san si n bẹ nibẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Sàárà kò mọ lori nǹkan ti èèyàn n yọ jáde ninu dúkìá, bi ko ṣe pe o ko gbogbo oore ti ọmọniyan n ṣe tàbí sọ sínú, ti o si maa de ọdọ ẹlòmíràn.
  2. O n bẹ nibẹ isẹnilojukokoro lati maa ṣe dáadáa ati gbogbo nǹkan ti àǹfààní ba n bẹ nibẹ fun ẹlòmíràn.
  3. Ki èèyàn ma fi ojú kere dáadáa kankan, kódà ki o kéré.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (67)