+ -

عن أنس بن مالك رضي الله عنه أن رسول الله صلى الله عليه وسلم قال:
«مَنْ أَحَبَّ أَنْ يُبْسَطَ لَهُ فِي رِزْقِهِ، وَيُنْسَأَ لَهُ فِي أَثَرِهِ، فَلْيَصِلْ رَحِمَهُ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 5986]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni tí ó bá fẹ́ ki wọn gbòòrò arisiki fun oun, ti o si fẹ ki ẹmi oun gùn, ki o maa da ẹbí pọ”.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 5986]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣeni lojukokoro lati maa da ẹbí pọ pẹ̀lú abẹwo ati apọnle ti ara ati ti owó, ati nǹkan ti o yatọ si i, oun si tun ni okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti èdè Fulani Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ar-Rọhim ni àwọn mọlẹbi ni igun ti bàbá ati iya, bi o ba ṣe sunmọ si naa ni o ṣe ni ẹtọ láti da a pọ̀ tó.
  2. Ẹsan maa wa latara iran iṣẹ ni, ẹni tí ó bá da ẹbí rẹ pọ pẹ̀lú dáadáa, Ọlọhun maa da a pọ̀ nibi ọjọ́-orí rẹ ati arisiki rẹ.
  3. Dida ẹbí pọ jẹ okùnfà gbígbòòrò arisiki ati ẹmi gígùn, bi o tilẹ̀ jẹ́ pé àsìkò ti èèyàn maa lò laye ati arisiki ti ni gbèdéke, ṣùgbọ́n o tun le jẹ ìbùkún nibi arisiki ati ọjọ́-orí, o maa wa fi ìgbésí ayé rẹ ṣe nǹkan ti o maa pọ ti o si maa ṣe àǹfààní ju nǹkan ti ẹlòmíràn maa ṣe lọ, àwọn kan sọ pé alekun arisiki ati ọjọ́-orí naa maa jẹ alekun gidi. Ọlọhun ni O ni imọ julọ.