عن أبي هريرة رضي الله عنه قال: قال رسول الله صلى الله عليه وسلم:
«لَا تَجْعَلُوا بُيُوتَكُمْ قُبُورًا، وَلَا تَجْعَلُوا قَبْرِي عِيدًا، وَصَلُّوا عَلَيَّ؛ فَإِنَّ صَلَاتَكُمْ تَبْلُغُنِي حَيْثُ كُنْتُمْ».
[حسن] - [رواه أبو داود] - [سنن أبي داود: 2042]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurairah - ki Ọlọhun yọnu si i - ó ṣo pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
“Ẹ má ṣe sọ ilé yín di saare, ẹ sì má sọ saare mi di àáye àjọ̀dún, ẹ maa ṣe asalatu fún mi; dajudaju asalatu yín ó kàn mi lara lati ibikibi ti ẹ ba wa.
[O daa] - [Abu Daud ni o gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 2042]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n kọ̀ fún wa níbi kí a má maa ki ìrun ninu awọn ile wa, tí awọn ile naa yio waa da gẹgẹ bii itẹ́ awọn òkú, tí ẹnikẹni kò gbọdọ̀ kirun nibẹ. O sì kọ̀ fun wa lati maa ṣe àbẹ̀wò saare rẹ̀ léraléra ati imaa kójọ sibẹ ni igba gbogbo; nitori pe iyẹn jẹ́ ọna kan tí ó lè mu wa wọ inu ẹbọ. Ó paṣẹ pe ki a maa tọrọ ìkẹ́ ati ìgẹ̀ fun oun ni ibikibi lori ilẹ aye; nitori pe iyẹn yoo kàn án lara lati ọdọ ẹniti ó sunmọ ati ẹniti ó jinna bakan naa, nitori naa a o ni bukata si ki a maa paara ibi saare rẹ̀.