عَنْ عَلِيٍّ رضي الله عنه قَالَ:
كُنْتُ رَجُلًا مَذَّاءً وَكُنْتُ أَسْتَحْيِي أَنْ أَسْأَلَ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ لِمَكَانِ ابْنَتِهِ فَأَمَرْتُ الْمِقْدَادَ بْنَ الْأَسْوَدِ فَسَأَلَهُ فَقَالَ: «يَغْسِلُ ذَكَرَهُ وَيَتَوَضَّأُ».
وَلِلبُخَاريِّ: فَقَالَ: «تَوَضَّأْ وَاغْسِلْ ذَكَرَكَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح مسلم: 303]
المزيــد ...
Lati ọdọ Aliy- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Mo jẹ ọkùnrin kan ti o maa n da atọ ireke lọpọlọpọ, mo maa n tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nitori ipo ọmọbinrin rẹ, mo wa pa Miqdad ọmọ Al-Aswad láṣẹ o si beere lọwọ rẹ, o sọ pe: "O maa fọ nnkan ọmọkunrin rẹ yoo si ṣe aluwala ". O n bẹ fun Bukhari: O sọ pe: "Ṣe aluwala ki o si fọ nnkan ọmọkunrin rẹ".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Muslim - 303]
Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe atọ ireke- oun ni omi funfun ti kò ki ti o maa n fà tìkọ̀, o maa n jade lati inu nnkan ọmọkunrin nigba adun tabi ṣíwájú ibalopọ- maa n jáde lara oun lọpọlọpọ, Ko si mọ bi o ṣe maa ṣe pẹlu jijade rẹ, o wa tiju lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-; nitori pe o jẹ ọkọ Fatimah ọmọbìnrin Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, O wa tọrọ lọdọ Miqdad ọmọ Al-Aswad lati beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa ìyẹn, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Ki o fọ nnkan ọmọkunrin rẹ lẹyin naa ki o ṣe aluwala.