+ -

عَنْ أَبِي أَيُّوبَ الأَنْصَارِيِّ رضي الله عنه أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«إِذَا أَتَيْتُمُ الغَائِطَ فَلاَ تَسْتَقْبِلُوا القِبْلَةَ، وَلاَ تَسْتَدْبِرُوهَا وَلَكِنْ شَرِّقُوا أَوْ غَرِّبُوا» قَالَ أَبُو أَيُّوبَ: فَقَدِمْنَا الشَّأْمَ فَوَجَدْنَا مَرَاحِيضَ بُنِيَتْ قِبَلَ القِبْلَةِ فَنَنْحَرِفُ، وَنَسْتَغْفِرُ اللَّهَ تَعَالَى.

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 394]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu 'Ayyub Al-Ansari- ki Ọlọhun yọnu si i-, dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
«Ti ẹ ba ti wa si aaye igbọnsẹ yin ẹ ko gbọdọ da oju kọ kibula, ẹ ko si tun gbọdọ da ẹyin kọ ọ, amọ ẹ daju kọ ila oorun tabi iwọ oorun» Abu Ayyūb sọ pe: A wa si Shām ti a si ri awọn ile igbọnsẹ ti wọn ti mọ daju kọ kibula, nitori naa a maa n yẹ si ẹgbẹ, ti a si tun maa n wa aforijin Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 394]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun ẹni ti o ba fẹ gbọ bukaata itọ tabi igbẹ ki o da oju kọ kibula ati agbegbe kaaba, ki o si ma tun da ẹyin kọ ọ; amọ o jẹ dandan fun un ki o yi si ila oorun tabi iwọ oorun ti kibula rẹ ba jọ kibula awọn ara Madinah. Lẹyin naa ni Abu Ayyūb wa funni ni iro pe nígbà tí wọn de Shām wọn ri awọn ile igbọnsẹ nibẹ ti wọn ti pese kalẹ fun gbigbọ bukaata ti wọn da oju wọn kọ kaaba, nitori naa wọn maa n yi ara wọn kuro ni kibula, ti wọn si tun maa n toro aforijin Ọlọhun pẹlu bẹ́ẹ̀.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Thai Pashto Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti ede Madagascar Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọgbọn ti o n bẹ nibi ìyẹn ni gbigbe kaaba abiyi tobi ati ṣiṣe aponle rẹ.
  2. Wíwá aforijin lẹyin jijade kuro ni aaye igbọ bukaata.
  3. Didara ikọnilẹkọọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -; latari pe nígbà tí o darukọ nkan ti wọn kọ, o tọka si eyi ti o lẹtọọ naa.