+ -

«لَا يُمْسِكَنَّ أَحَدُكُمْ ذَكَرَهُ بِيَمِينِهِ وَهُوَ يَبُولُ، وَلَا يَتَمَسَّحْ مِنَ الْخَلَاءِ بِيَمِينِهِ، وَلَا يَتَنَفَّسْ فِي الْإِنَاءِ».
[صحيح] - [متفق عليه]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Qatāda- ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe:
«Ẹnikẹni ninu yin o gbọdọ fi ọwọ ọtun rẹ mu nkan ọmọkunrin rẹ nigba ti o ba n tọ, ko si gbọdọ fi ọwọ rẹ ọtun ṣe imọra nibi igbọnsẹ, ko si gbọdọ fẹ atẹgun si inu ife imumi».

O ni alaafia - Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn ẹkọ kan; nigba ti o kọ ki ọkunrin fi ọwọ ọtun rẹ gba oko re mu nigba ti o ba n tọ, ati lati mu ẹgbin kuro niwaju tabi ẹyin pẹlu ọwọ rẹ ọtun; nitori pe ọwọ ọtun wọn pese rẹ fun awọn iṣẹ rere ni, Gẹgẹ bi o ṣe kọ fun ọmọniyan lati mi sinu igba ti o fẹ mu nibẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Ti èdè Sawahili Thai Assamese Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ti èdè Kyrgyz Ti èdè Dari
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Alaye gbigba iwaju Isilaamu ninu awọn ẹkọ ati imọtoto.
  2. Jijina si awọn nnkan ìdọ̀tí, ti ko ba wa si ibuyẹ afi ki o ṣe e, ki o yaa jẹ pẹlu ọwọ osi.
  3. Alaye iyi ti o n bẹ fun ọwọ ọtun ati ọla ti o n bẹ fun un lori ọwọ osi.
  4. Pipe Sharia Isilaamu ati kikun awọn ẹkọ rẹ.