عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه عَنِ النَّبِيِّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«أَمَا يَخْشَى أَحَدُكُمْ - أَوْ: لاَ يَخْشَى أَحَدُكُمْ - إِذَا رَفَعَ رَأْسَهُ قَبْلَ الإِمَامِ، أَنْ يَجْعَلَ اللَّهُ رَأْسَهُ رَأْسَ حِمَارٍ، أَوْ يَجْعَلَ اللَّهُ صُورَتَهُ صُورَةَ حِمَارٍ».

[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 691]
المزيــد ...

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Ṣe ẹnikọọkan yin o maa bẹru - tabi: Ẹnikọọkan yin o bẹru - nigba ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu, ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan di aworan Kẹtẹkẹtẹ».

[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 691]

Àlàyé

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye adehun iya ti o le gidi fun ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju imaamu rẹ, pẹlu pe ki Ọlọhun o sọ ori rẹ di ori Kẹtẹkẹtẹ, tabi ki o sọ aworan rẹ di aworan Kẹtẹkẹtẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. O n bẹ fun ero ẹyin pẹlu imaamu rẹ ìṣesí mẹẹrin: Wọn kọ kuro nibi mẹta, oun naa ni: Gbigba iwaju ati biba dọgba ati pipẹ lẹyin, ati pe eyi ti wọn ṣe lofin fun ero ẹyin ni: Titẹle imaamu.
  2. Jijẹ dandan itẹle ero ẹyin fun imaamu rẹ ninu irun.
  3. Adehun iya pẹlu yiyi aworan ẹni ti o ba gbe ori rẹ soke ṣaaju Imaamu sí aworan Kẹtẹkẹtẹ nkan ti o rọrun ni, oun si wa ninu pipa aworan da.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (55)