عن عَائِشَةَ رضيَ الله عنها قالت: إِنِّي سمعْتُ رسولَ الله صلى الله عليه وسلم يقول:
«لَا صَلَاةَ بِحَضْرَةِ الطَّعَامِ، وَلَا هُوَ يُدَافِعُهُ الْأَخْبَثَانِ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 560]
المزيــد ...
Lati ọdọ ‘Aaisha- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Dajudaju mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe:
“ko si irun pẹlu ikalẹ ounjẹ, tabi nigba ti igbẹ ati itọ ba n gbọ̀n ọ́n”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 560]
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi kiki irun pẹlu ikalẹ ounjẹ ti ẹmi olukirun n fa síbẹ̀, ti ọkan rẹ si n so mọ ọn.
Gẹgẹ bẹẹ ni o ṣe kọ kuro nibi kiki irun pẹlu dídá Al-Akhbathaan- awọn mejeeji ni itọ ati igbẹ- padà, nitori kiko airoju rẹ pẹlu dídá ẹgbin náà padà.