عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رضي الله عنه قَالَ: قَالَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ:
«أَسْوَأُ النَّاسِ سَرَقَةً الَّذِي يَسْرِقُ صَلَاتَهُ» قَالَ: وَكَيْفَ يَسْرِقُ صَلَاتَهُ؟ قال: «لَا يُتِمُّ رُكُوعَهَا، وَلَا سُجُودَهَا».
[صحيح] - [رواه ابن حبان] - [صحيح ابن حبان: 1888]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti ole jija, ni ẹni ti o n ja irun rẹ lole” o sọ pe: Bawo ni o ṣe maa ja irun rẹ lole? O sọ pe: “ Ko nii rukuu dáadáa, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣẹpe”.
[O ni alaafia] - [Ibnu Hibbaan ni o gba a wa] - [Sọhiihu ti Ibnu Hibbaan - 1888]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o buru julọ ninu awọn eniyan ni ti iwa buruku nibi ole jija ni ẹni ti o maa n jale nibi irun rẹ; ìyẹn rí bẹ́ẹ̀ nitori pe ẹni ti o ba mu owo ẹlomiran, o ṣeeṣe ki o ṣe anfaani pẹlu rẹ ni aye, yatọ si ole yii, dajudaju oun ja ẹtọ ara rẹ lole ninu ẹsan ati laada, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, bawo ni o maa ṣe jale ninu irun rẹ? O sọ pe: Ko nii ṣe rukuu rẹ laṣepe, ko si nii ṣe iforikanlẹ rẹ laṣepe; ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu pe ki o maa kanju nibi rukuu ati iforikanlẹ, ti ko nii mu mejeeji wa ni ona ti o pe.