+ -

عن ابن عباس رضي الله عنهما:
كان النبي صلى الله عليه وسلم يقول بين السجدتين: «اللَّهمَّ اغْفِرْ لي، وارْحَمْنِي، وعافِني، واهْدِني، وارزقْنِي».

[حسن بشواهده] - [رواه أبو داود والترمذي وابن ماجه وأحمد] - [سنن أبي داود: 850]
المزيــد ...

Lati ọdọ ọmọ Abbās – ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- pé:
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n sọ laarin iforikanlẹ mejeeji pe: «Allāhummọ igfir li, warhamnī, wa ‘āfinī, wahdinī, warzuqnī».

[O daa pẹlu awọn ẹri rẹ] - [Abu Daud ati Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Abu Daud - 850]

Àlàyé

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe adua laarin iforikanlẹ mejeeji nibi irun rẹ pẹlu awọn adua máàrún yii ti Musulumi ni bukaata ti o tobi si i, ti o si tun ko oore ayé àti ti ọjọ ikẹhin sinu, bii wiwa aforijin ati idaabobo awọn ẹṣẹ ati ṣiṣe amojukuro nibẹ, ati pípé ikẹ, ati lila kuro nibi awọn iruju ati awọn adun ati awọn aisan ati idakọlẹ, ati ibeere imọna lọdọ Ọlọhun sibi ododo pẹlu ifẹsẹmulẹ lori rẹ, ati níní ìgbàgbọ́ àti imọ àti iṣẹ oloore, ati níní dukia halaali ti o mọ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Ṣáínà Èdè Páṣíà Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Ará Japan Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè Kannada Ti èdè ìlú Ukraine
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣiṣe adua yii lofin nibi ijokoo ti o wa laarin iforikanlẹ mejeeji.
  2. Ọla ti n bẹ fun àwọn adua yii latari nkan ti o ko sinu ni oore ayé àti ọjọ ìkẹhìn.