عَنْ أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللَّهُ عَنْهُ قَالَ:
كَانَ رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ يَدْعُو وَيَقُولُ: «اللَّهُمَّ إِنِّي أَعُوذُ بِكَ مِنْ عَذَابِ القَبْرِ، وَمِنْ عَذَابِ النَّارِ، وَمِنْ فِتْنَةِ المَحْيَا وَالمَمَاتِ، وَمِنْ فِتْنَةِ المَسِيحِ الدَّجَّالِ».
وفِي لَفْظٍ لِمُسْلِمٍ: «إِذَا فَرَغَ أَحَدُكُمْ مِنَ التَّشَهُّدِ الْآخِرِ، فَلْيَتَعَوَّذْ بِاللهِ مِنْ أَرْبَعٍ: مِنْ عَذَابِ جَهَنَّمَ، وَمِنْ عَذَابِ الْقَبْرِ، وَمِنْ فِتْنَةِ الْمَحْيَا وَالْمَمَاتِ، وَمِنْ شَرِّ الْمَسِيحِ الدَّجَّالِ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 1377]
المزيــد ...
Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n ṣe adua ti o si maa n sọ pe: «Irẹ Ọlọhun dajudaju emi wa iṣọra pẹlu Rẹ kuro nibi iya saare, ati nibi iya ina, ati nibi fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi fitina al-Masiihu ad-Dajjāl». Nibi ti gbolohun ti Muslim: «Ti ẹnikẹni ninu yin ba ti pari ataaya igbẹyin, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi awọn nkan mẹẹrin: Nibi iya jahannamọ, ati nibi iya saare, ati nini fitina iṣẹmi ati iku, ati nibi aburu al-Masiihu ad-Dajjāl».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 1377]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti maa n wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibi nkan mẹẹrin, lẹyin ataaya igbẹyin ati siwaju salamọ ninu irun, o si tun pa wa laṣẹ ki a maa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro nibẹ,
Ikinni: Nibi iya saare.
Ẹẹkeji: Nibi iya ina ati pe ìyẹn ni ọjọ igbedide.
Ẹẹkẹta: Nibi fitina iṣẹmi bi awọn adun aye ti o jẹ eewọ ati awọn iruju ti maa n sọni nu, ati nibi fitina iku, ìyẹn ni àsìkò pipọka iku, bii yiyẹ kuro ninu Isilaamu tabi Sunnah, tabi fitina saare gẹgẹ bii ibeere awọn malaika mejeeji.
Ẹẹkẹrin: Fitina al-Masiihu ad-Dajjāl eleyii ti yio jade ni igbẹyin aye, Ọlọhun yio fi i dan awọn ẹru Rẹ wo; o wa darukọ rẹ lọ́tọ̀ latari titobi fitina rẹ ati isọninu rẹ.