عَنِ ابْنِ أَبِي أَوْفَى رضي الله عنه قَالَ:
كَانَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ إِذَا رَفَعَ ظَهْرَهُ مِنَ الرُّكُوعِ قَالَ: «سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، اللَّهُمَّ رَبَّنَا لَكَ الْحَمْدُ، مِلْءَ السَّمَاوَاتِ وَمِلْءَ الْأَرْضِ وَمِلْءَ مَا شِئْتَ مِنْ شَيْءٍ بَعْدُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 476]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Abu Aofaa- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu, o maa sọ pé: “Sami’alloohu liman hamidaHu, Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 476]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti gbe ẹyin rẹ dide lati rukuu ninu irun, o maa n sọ pe: “Sami’alloohu liman hamidaHu”, o n túmọ̀ si: Dajudaju ẹni ti o ba dupẹ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- maa da a lohun, yio si gba ọpẹ rẹ ati ẹyin rẹ, yio si san lẹsan, lẹyin naa, o maa dupẹ fun Ọlọhun pẹlu sisọ pe: “Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, milhas samoowaati wa milhal ardi wa milha maa shi-ita min shaihin bahdu”, ni ọpẹ kan ti o maa kun awọn sanmọ ati awọn ilẹ ati nnkan ti o n bẹ laaarin mejeeji, ti o si n kun nnkan ti Ọlọhun ba fẹ ninu nnkan kan.