عَنْ حِطَّانَ بْنِ عَبْدِ اللهِ الرَّقَاشِيِّ قَالَ: صَلَّيْتُ مَعَ أَبِي مُوسَى الْأَشْعَرِيِّ صَلَاةً، فَلَمَّا كَانَ عِنْدَ الْقَعْدَةِ قَالَ رَجُلٌ مِنَ الْقَوْمِ: أُقِرَّتِ الصَّلَاةُ بِالْبِرِّ وَالزَّكَاةِ، قَالَ: فَلَمَّا قَضَى أَبُو مُوسَى الصَّلَاةَ وَسَلَّمَ انْصَرَفَ فَقَالَ: أَيُّكُمُ الْقَائِلُ كَلِمَةَ كَذَا وَكَذَا؟ قَالَ: فَأَرَمَّ الْقَوْمُ، ثُمَّ قَالَ: أَيُّكُمُ الْقَائِلُ كَلِمَةَ كَذَا وَكَذَا؟ فَأَرَمَّ الْقَوْمُ، فَقَالَ: لَعَلَّكَ يَا حِطَّانُ قُلْتَهَا؟ قَالَ: مَا قُلْتُهَا، وَلَقَدْ رَهِبْتُ أَنْ تَبْكَعَنِي بِهَا، فَقَالَ رَجُلٌ مِنَ الْقَوْمِ: أَنَا قُلْتُهَا، وَلَمْ أُرِدْ بِهَا إِلَّا الْخَيْرَ، فَقَالَ أَبُو مُوسَى: أَمَا تَعْلَمُونَ كَيْفَ تَقُولُونَ فِي صَلَاتِكُمْ؟ إِنَّ رَسُولَ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ خَطَبَنَا فَبَيَّنَ لَنَا سُنَّتَنَا وَعَلَّمَنَا صَلَاتَنَا، فَقَالَ:
«إِذَا صَلَّيْتُمْ فَأَقِيمُوا صُفُوفَكُمْ، ثُمَّ لِيَؤُمَّكُمْ أَحَدُكُمْ فَإِذَا كَبَّرَ فَكَبِّرُوا، وَإِذْ قَالَ: {غَيْرِ الْمَغْضُوبِ عَلَيْهِمْ وَلا الضَّالِّينَ} [الفاتحة: 7]، فَقُولُوا: آمِينَ، يُجِبْكُمُ اللهُ، فَإِذَا كَبَّرَ وَرَكَعَ فَكَبِّرُوا وَارْكَعُوا، فَإِنَّ الْإِمَامَ يَرْكَعُ قَبْلَكُمْ، وَيَرْفَعُ قَبْلَكُمْ»، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «فَتِلْكَ بِتِلْكَ، وَإِذَا قَالَ: سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، فَقُولُوا: اللَّهُمَّ رَبَّنَا لَكَ الْحَمْدُ، يَسْمَعِ اللهُ لَكُمْ، فَإِنَّ اللهَ تَبَارَكَ وَتَعَالَى قَالَ عَلَى لِسَانِ نَبِيِّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: سَمِعَ اللهُ لِمَنْ حَمِدَهُ، وَإِذَا كَبَّرَ وَسَجَدَ فَكَبِّرُوا وَاسْجُدُوا، فَإِنَّ الْإِمَامَ يَسْجُدُ قَبْلَكُمْ وَيَرْفَعُ قَبْلَكُمْ»، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «فَتِلْكَ بِتِلْكَ، وَإِذَا كَانَ عِنْدَ الْقَعْدَةِ فَلْيَكُنْ مِنْ أَوَّلِ قَوْلِ أَحَدِكُمُ: التَّحِيَّاتُ الطَّيِّبَاتُ الصَّلَوَاتُ لِلهِ، السَّلَامُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللهِ الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ».
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 404]
المزيــد ...
Lati ọdọ Hitton ọmọ Abdullahi Ar-Roqooshiy o sọ pe: Mo kirun kan pẹlu Abu Musa Al-Ash'ariy, nigba ti o wa lori ìjókòó, arakunrin kan ninu ijọ sọ pe: Wọn ti da irun pọ mọ ṣíṣe daadaa ati saka, o sọ pe: Nigba ti Abu Musa kirun tan ti o si salamọ, o kọ ju sẹ́yìn, ni o wa sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? O sọ pe: Ni awọn èèyàn ba dakẹ, lẹyin naa o sọ pe: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun bayii bayii? Ni awọn èèyàn ba dakẹ, o sọ pe: Boya iwọ Hitton lo sọ ọ? O sọ pe: Mi ko sọ ọ, mo bẹru pe ki o ma bu mi nitori rẹ, arakunrin kan ninu wa sọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ pe: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ nibi irun yin ni? Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọ̀rọ̀ ti o si ṣàlàyé sunnah wa fun wa ti o si kọ wa ni irun wa, o wa sọ pe:
"Ti ẹ ba ti fẹ kirun, ẹ gbe saafu yin dìde, lẹyin naa ki ẹnikan ninu yin ṣe imaamu fun yín, ti o ba ti kabara, ki ẹyin naa kabara, ti o ba sọ pe: (Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7), ki ẹ sọ pé: Aamiin, Ọlọhun maa da yin lóhùn, ti o ba ti kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu, dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín, yio si gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamd, Ọlọhun maa gbọ́ yín, dajudaju Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Sami'alloohu liman hamidaHu, ti o ba ti kabara ti o forikanlẹ, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si forikanlẹ, dájúdájú imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú yín, o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín", ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pe: "Iyẹn pẹlu ìyẹn, ti o ba ti wa lori ìjókòó, ki ọrọ akọkọ ẹni kọọkan ninu yin jẹ: At-tahiyyatu t-tayyibaatus-salawaatu lillah, as-salamu ‘alayka ayyuha’n-Nabiyyu wa rahmatulLaahi wa barakatuhu, as-salamu ‘alayna wa alaa ibaadil Laahis sọọlihiin, ash'hadu an laa ilaaha illal Loohu wa ash'hadu anna Muhammadan abduhuu wa rọsuuluhuu".
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 404]
Saabe ti o n jẹ Abu Musa Al-Ash'ariy- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun kan, nigba ti o wa ni ijokoo ti ataya wa nibẹ, arakunrin kan ninu awọn ti wọn kirun lẹyin rẹ sọ pe: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani, nigba ti Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- kirun tan, o doju kọ awọn ero ẹyin, ni o wa bi wọn leere pé: Ewo ninu yin lo sọ gbolohun: Wọn da irun pọ mọ daadaa ati saka ninu Kuraani?! Ni awọn èèyàn ba dakẹ, ti ẹnikẹni ko sọ̀rọ̀ ninu wọn, ni o ba paara ibeere naa lẹẹkan si, nigba ti ẹnikẹni ko da a lohun, Abu Musa- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: Boya iwọ Hittọọn ni o sọ ọ! Nitori ìgboyà rẹ ati asunmọ rẹ ati asopọ rẹ pẹlu rẹ, ninu nnkan ti kikẹfin rẹ ko lee ko suta ba a, ati pe ki o le ti ẹni ti o ṣe e gangan jade lati jẹwọ, ni Hittọọn wa sọ pe ko ri bẹ́ẹ̀, o wa sọ pe: Mo bẹru ki o ma bu mi ti o n lero pe emi ni mo sọ ọ; ibi yii ni arakunrin kan ti sọ ninu awọn ijọ pe: Emi ni mo sọ ọ, mi ko si gbero nnkan kan pẹlu rẹ afi dáadáa, ni Abu Musa wa sọ ni ẹni ti o n kọ ọ pé: Ṣe ẹ ko mọ bi ẹ ṣe ma maa sọ lori irun yin ni?! Eleyii jẹ àtakò lati ọdọ rẹ, lẹyin naa Abu Musa wa sọ pe dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba awọn sọ̀rọ̀ ni ọjọ kan, ti o ṣàlàyé Sharia wọn fun wọn, ti o kọ wọn ni irun wọn, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé:
Ti ẹ ba fẹ kirun, ki ẹ ya gbe saafu dide ki ẹ si duro tọ́ nibẹ, lẹyin naa ki ẹnikan ninu wọn ṣe imaamu fun awọn eniyan, ti imaamu ba ti kabara wiwọ inu irun, ki ẹyin naa kabara iru rẹ, ti o ba ti ka Fatiha ti o ba wa de: ((Ghayril-maghdoobi ‘alaihim wa lad-daaalleen) (Al- Fatiha: 7)), ki ẹ sọ pe: Aamiin; ti ẹ ba ṣe bẹẹ Ọlọhun maa gba adura yin, ti o ba kabara ti o si rukuu, ki ẹyin naa kabara ki ẹ si rukuu; dajudaju imaamu maa rukuu ṣíwájú yín o si maa gbe ori dide ṣíwájú yín, nitori naa ẹ ko gbọdọ ṣíwájú rẹ; nitori pe asiko ti imaamu gba waju nibẹ lati ṣíwájú yin rukuu, ilọra yin ni rukuu lẹyin ti imaamu ti gbori kuro maa di i fun yin, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn rukuu yin maa da gẹgẹ bii odiwọn rukuu rẹ, ti imaamu ba sọ pe: Sami'alloohu liman hamidaHu, ki ẹ sọ pé: Allahumo Robbanaa wa laKal hamdu, ti awọn ero ẹyin ba sọ ìyẹn, dajudaju Ọlọhun- mimọ ni fun Un- maa gbọ́ adura wọn ati ọrọ wọn, nitori pe Ọlọhun- ibukun ni fun orúkọ Rẹ, ti ọla Rẹ ga- sọ lori ahọn Anabi Rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pé: Samihal Loohu liman hamidaHu, lẹyin naa ti imaamu ba kabara ti o si forikanlẹ, o jẹ dandan fun awọn ero ẹyin lati kabara ki wọn si forikanlẹ, dajudaju imaamu maa forikanlẹ ṣíwájú wọn, o si maa gbe ori dide ṣíwájú wọn, iru asiko yẹn pẹlu asiko yẹn, odiwọn iforikanlẹ ero ẹyin maa da gẹgẹ bii odiwọn iforikanlẹ imaamu, ti o ba wa lori ijokoo ataya, ki akọkọ ọrọ olukirun jẹ: At-tahiyyaatu toyyibaatus solawaatu lillah"
Ọla ati ṣiṣẹku ati titobi gbogbo rẹ pata jẹ ẹtọ fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-, gẹgẹ bẹ́ẹ̀ naa ni awọn irun maraarun-un, gbogbo rẹ pata jẹ ti Ọlọhun, "As-salaamu 'alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu 'alayna wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen", ẹ pe Ọlọhun fun lila kuro nibi gbogbo aleebu ati adinku ati ibajẹ; a maa ṣẹsa Anabi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pẹlu àlàáfíà, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun ara wa, lẹyin naa a maa tọrọ alaafia fun awọn ẹru Ọlọhun ti wọn jẹ ẹni rere ti wọn ṣe nnkan ti o jẹ dandan fun wọn ninu awọn iwọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ati awọn iwọ awọn ẹru Rẹ, lẹyin naa, a maa jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Ọlọhun, a si n jẹrii pe dajudaju Muhammad ẹru Rẹ ni ati ojiṣẹ Rẹ.