عَنِ ابْنَ مَسْعُودٍ رضي الله عنه قَالَ:
عَلَّمَنِي رَسُولُ اللَّهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ، وَكَفِّي بَيْنَ كَفَّيْهِ، التَّشَهُّدَ، كَمَا يُعَلِّمُنِي السُّورَةَ مِنَ القُرْآنِ: «التَّحِيَّاتُ لِلَّهِ، وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ، السَّلاَمُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللَّهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلاَمُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللَّهِ الصَّالِحِينَ، أَشْهَدُ أَنْ لاَ إِلَهَ إِلَّا اللَّهُ، وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ».
وفي لفظ لهما: «إِنَّ اللهَ هُوَ السَّلَامُ، فَإِذَا قَعَدَ أَحَدُكُمْ فِي الصَّلَاةِ فَلْيَقُلْ: التَّحِيَّاتُ لِلَّهِ وَالصَّلَوَاتُ وَالطَّيِّبَاتُ السَّلَامُ عَلَيْكَ أَيُّهَا النَّبِيُّ وَرَحْمَةُ اللهِ وَبَرَكَاتُهُ، السَّلَامُ عَلَيْنَا وَعَلَى عِبَادِ اللهِ الصَّالِحِينَ، فَإِذَا قَالَهَا أَصَابَتْ كُلَّ عَبْدٍ لِلَّهِ صَالِحٍ فِي السَّمَاءِ وَالْأَرْضِ، أَشْهَدُ أَنْ لَا إِلَهَ إِلَّا اللهُ، وَأَشْهَدُ أَنَّ مُحَمَّدًا عَبْدُهُ وَرَسُولُهُ، ثُمَّ يَتَخَيَّرُ مِنَ الْمَسْأَلَةِ مَا شَاءَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 6265]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ mi ni ataya, ti atẹlẹwọ mi wa laaarin atẹlẹwọ rẹ mejeeji, gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ mi ni Surah ninu Kuraani: "At-tahiyyaatu lillah, was solawaatu wat toyyibaatu, as salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa 'ibaadillahis soliheen, ash-hadu an laa ilaaha illallohu wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu". Ninu ẹgbawa kan ti o jẹ ti awọn mejeeji: "Dajudaju Ọlọhun ni Ọba alaafia, ti ẹnikẹni ninu yin ba jokoo nibi irun, ki o ya sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah was solawaatu wat toyyibaatu, As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu, as-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen. Ti o ba ti sọ ọ, o maa ba gbogbo ẹru Ọlọhun rere ni oke ati ilẹ, ash-hadu an laa ilaaha illallohu, wa ash-hadu anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu, lẹyin naa o maa ṣe ẹṣa nnkan ti o ba fẹ ninu ibeere".
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 6265]
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- ni ataya ti wọn maa n ka lori irun, o wa fi ọwọ rẹ si ọwọ rẹ mejeeji, lati jẹ ki o kọ ibi ara si i. Gẹgẹ bi o ṣe maa n kọ ọ ni Surah ninu Kuraani ninu nnkan ti o tọka lori iko akolekan Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- si ataya yii ni gbolohun ati ni ìtumọ̀. O si sọ pe: "At-tahiyyaatu lillah": Oun ni gbogbo ọrọ ati iṣẹ ti o da lori igbetobi, gbogbo ẹ ni o tọ si Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn. "As-solawaatu": Oun ni ìrun ti a mọ, ọran-anyan rẹ ati awọn nafila rẹ jẹ ti Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "At-toyyibaatu": Òun ni awọn ọrọ ati awọn iṣẹ ati awọn iroyin ti wọn daa ti wọn si n da lori pipe, gbogbo rẹ tọ si Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga-. "As-salaamu alaika ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu": Adura ni o jẹ fun un pẹlu lila kuro nibi gbogbo aleebu ati nnkan ti a koriira, ati alekun ati ọpọlọpọ ninu gbogbo oore. "As-salaamu alaina wa 'alaa'ibaadillahis soliheen": Adura ni o jẹ pẹlu ọlà fun olukirun ati fun gbogbo ẹru rere ni sanmọ ati ilẹ. "Ash-hadu an laa ilaaha illallohu": O n túmọ̀ si pe mo n fi i rinlẹ ni ifirinlẹ ododo pẹlu rẹ pe ko si ẹni ti a le jọsin fun lododo afi Ọlọhun. "Wa anna Muhammadan 'abduHu wa rosuuluHu": Mo n fi ijẹ ẹru ati ìránṣẹ́ ti o jẹ opin rinlẹ fun un.
Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe olukirun lojukokoro lati ṣe ẹṣa ninu adura ti o ba fẹ.