عن ابنِ عَبَّاسٍ رضي الله عنهما عن النبيِّ صلى الله عليه وسلم قال:
«أُمِرْتُ أَنْ أَسْجُدَ عَلَى سَبْعَةِ أَعْظُمٍ: عَلَى الْجَبْهَةِ وَأَشَارَ بِيَدِهِ عَلَى أَنْفِهِ، وَالْيَدَيْنِ، وَالرُّكْبَتَيْنِ، وَأَطْرَافِ الْقَدَمَيْنِ، وَلَا نَكْفِتَ الثِّيَابَ وَالشَّعَرَ».
[صحيح] - [متفق عليه] - [صحيح البخاري: 812]
المزيــد ...
Lati ọdọ ọmọ Abbās - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe:
«Wọn pa mi laṣẹ ki n fi ori kan'lẹ lori oríkèé meje: Lori iwaju ori, o si na ọwọ rẹ si imu rẹ, ati ọwọ mejeeji, ati orunkun mejeeji, ati awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji, ati pe ki a ma ka awọn aṣọ ati irun».
[O ni alaafia] - [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 812]
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun pa a laṣẹ nibi irun ki o fi oríkèé meje ninu awọn oríkèé ara rẹ kan'lẹ; awọn naa ni:
Alakọkọọ: Iwaju ori: Oun ni: Alawẹ oju ti o wa ni oke imu ati oju mejeeji, Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun o maa ba a, fi ọwọ rẹ si imu rẹ, ti o fihan pe iwaju ati imu jẹ ọkan ninu awọn meje naa, o si tẹnumọ pe ẹni ti o n fi ori kan ilẹ maa fi kan ilẹ pẹlu imu rẹ.
Oríkèé kejì ati ìkẹta: Ọwọ mejeeji.
Ẹlẹẹkẹrin ati Ẹlẹẹkarun-un: Orunkun mejeeji.
Ẹlẹẹkẹfa ati Ẹlẹẹkeje: Awọn ọmọ ika ẹsẹ mejeeji.
O si tun pa wa laṣẹ ki a ma so awọn irun wa, ki a si ma ka awọn aṣọ wa papọ nibi iforikanlẹ lati fi da aabo bo o; bi ko ṣe pe a maa da a silẹ titi ti yio fi kan ilẹ, nitori naa yio le'lẹ pẹlu awọn orikee ara naa.