عن حُذَيْفَةَ رضي الله عنه:
أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ كَانَ يَقُولُ بَيْنَ السَّجْدَتَيْنِ: «رَبِّ اغْفِرْ لِي، رَبِّ اغْفِرْ لِي».

[صحيح] - [رواه أبو داود والنسائي وابن ماجه وأحمد] - [سنن ابن ماجه: 897]
المزيــد ...

Lati ọdọ Huzeifah- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy”.

[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Nasaa'iy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa] - [Sunanu ti Ibnu Maajah - 897]

Àlàyé

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n sọ nibi ijokoo laaarin iforikanlẹ mejeeji pé: Robbi igfir liy, Robbi igfir liy, o si maa n paara rẹ.
Ìtumọ̀ Robbi igfir liy ni pé: Ki ẹru wa lati ọdọ Oluwa rẹ lati pa awọn ẹṣẹ rẹ rẹ ki O si bo awọn aleebu rẹ.

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ṣíṣe adura yii lofin laaarin iforikanlẹ mejeeji nibi irun ọran-anyan ati naafila.
  2. Ṣíṣe pipaara sisọ gbolohun: Robbi igfir liy lofin, ati pe iye igba ti o jẹ dandan ni ẹẹkan.
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn
Èdè: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Àlékún (58)