عن عُثْمَانَ بْنَ أَبِي الْعَاصِ رضي الله عنه:
أنه أَتَى النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، إِنَّ الشَّيْطَانَ قَدْ حَالَ بَيْنِي وَبَيْنَ صَلَاتِي وَقِرَاءَتِي يَلْبِسُهَا عَلَيَّ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «ذَاكَ شَيْطَانٌ يُقَالُ لَهُ خِنْزَِبٌ، فَإِذَا أَحْسَسْتَهُ فَتَعَوَّذْ بِاللهِ مِنْهُ، وَاتْفُلْ عَلَى يَسَارِكَ ثَلَاثًا»، قَالَ: فَفَعَلْتُ ذَلِكَ فَأَذْهَبَهُ اللهُ عَنِّي.
[صحيح] - [رواه مسلم] - [صحيح مسلم: 2203]
المزيــد ...
Lati ọdọ Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i-:
Dajudaju o wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan ti wa laaarin mi ati irun mi ati kika mi, ti o n da a ru mọ mi loju, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: "Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta", o sọ pe: Mo wa ṣe bẹẹ ni Ọlọhun ba mu u kuro lọdọ mi.
[O ni alaafia] - [Muslim gba a wa] - [Sọhiihu ti Muslim - 2203]
Uthman ọmọ Abul 'Aas- ki Ọlọhun yọnu si i- wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, dajudaju Shaitan kọdi laaarin mi ati laaarin irun mi, ti o kọ ipaya fun mi nibẹ, ti o da kika mi ru ti o si ko iyemeji ba mi nibẹ, Ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba sọ fun un pe: Ìyẹn ni Shaitan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ri eyi ti o si fura mọ ọn, dirọ mọ Ọlọhun, ki o si wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, ki o si fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ pẹlu itọ diẹ lẹẹmẹta, Uthman sọ pe: Mo ṣe nnkan ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pa mi láṣẹ pe ki n ṣe, ni Ọlọhun si mu u kuro lọdọ mi.