عن ابن عباس رضي الله عنهما قال:
جاءَ رجُلُ إلى النبي صلى الله عليه وسلم فقال: يا رسولَ اللهِ، إن أحدنا يجدُ في نفسِهِ -يُعرِّضُ بالشَّيءِ- لأَن يكونَ حُمَمَةً أحَبُّ إليه من أن يتكلَّم بِهِ، فقال: «اللهُ أكبرُ، اللهُ أكبرُ، الحمدُ لله الذي ردَّ كيدَه إلى الوسوسَةِ».
[صحيح] - [رواه أبو داود والنسائي في الكبرى] - [سنن أبي داود: 5112]
المزيــد ...
Lati ọdọ Ibnu Abbas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe:
Arakunrin kan wa ba Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, dajudaju ọ̀kan ninu wa n ri ninu ẹ̀mí rẹ- o n pẹ́ nǹkan náà sọ pẹ̀lú itọka- o nífẹ̀ẹ́ si ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ lọ, o wa sọ pe: “ Ọlọhun tobi Ọlọhun tobi, ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi".
[O ni alaafia] - [Abu Daud ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa nínú al-Kubrọ] - [Sunanu ti Abu Daud - 5112]
Arakunrin kan wa sọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Ojisẹ Ọlọhun, dajudaju ẹnikan ninu wa n ri alamọri kan ninu ẹ̀mí rẹ ti o wa sínú ẹ̀mí, ṣùgbọ́n o tobi láti sọ ọ jáde, débi pe o nífẹ̀ẹ́ ki oun jẹ eeru ju ki o sọ ọ jade lọ, Bayii ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe Ọlọhun tobi ni ẹẹmeji, o si dupẹ fun Ọlọhun pe O da ete èṣù pada si royiroyi lasan.