+ -

عَنْ جَابِرٍ رضي الله عنه قَالَ:
أَتَى النَّبِيَّ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ رَجُلٌ فَقَالَ: يَا رَسُولَ اللهِ، مَا الْمُوجِبَتَانِ؟ فَقَالَ: «مَنْ مَاتَ لَا يُشْرِكُ بِاللهِ شَيْئًا دَخَلَ الْجَنَّةَ، وَمَنْ مَاتَ يُشْرِكُ بِاللهِ شَيْئًا دَخَلَ النَّارَ»

[صحيح] - [رواه مسلم]
المزيــد ...

Lati ọdọ Jabir- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Arakunrin kan wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: Irẹ Òjíṣẹ́ Ọlọhun, ki ni nnkan meji naa ti wọn maa n sọ nǹkan di dandan? O sọ pe: “Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina".

O ni alaafia - Muslim gba a wa

Àlàyé

Arakunrin kan beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa pe iroyin meji naa wo ni yoo sọ wiwọ alujanna di dandan, ati ti yoo sọ wiwọ ina di dandan? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- da a lohun pe: Dajudaju ìròyìn ti yoo sọ wiwọ alujanna di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n jọsin fun Ọlọhun nikan ṣoṣo ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọn, Ati pe iroyin ti yoo sọ wiwọ ina di dandan ni ki ọmọniyan ku ti o si n da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun ti yoo wa orogun ati olubakẹgbẹ fun Ọlọhun nibi ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ tabi nibi jijẹ Oluwa Rẹ tabi nibi awọn orukọ Rẹ ati awọn iroyin Rẹ.

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Tọ́kì Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Ti Kurdish Èdè Hausa Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Burmese Thai Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Ọla ti o n bẹ fun imu Ọlọhun ni Ọkan ati pe ẹni ti o ba ku ni olugbagbọ ododo ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna.
  2. Ewu ti o n bẹ fun ẹbọ, ati pe ẹni ti o ba ku ti o n da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina.
  3. Àwọn ẹlẹṣẹ nínú awọn ti wọn mu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo wa ni abẹ fifẹ Ọlọhun ti O ba fẹ yoo fi iya jẹ wọn, ti O ba si fẹ yoo forí jin wọn, lẹyin naa ìkángun wọn maa jẹ alujanna.