Ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn hadiisi

Mo fi Ẹni ti ẹmi Muhammad n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹnikẹni ko nii gbọ́ nipa mi ninu ìjọ yìí, Juu ni tabi Nasara, lẹyin naa o wa ku ti ko si ni igbagbọ pẹlu nnkan ti wọn fi ran mi, afi ko wa ninu awọn ara ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Egbe Ọlọhun ko lọ maa ba awọn Juu ati Nasara, ti wọn mu awọn saare awọn Anabi wọn ni mọsalasi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọlọhun, má ṣe sọ saare mi di òrìṣà
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Èmi ni Olùrọrọ̀ julọ tayọ níní orogún. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kan, ti o mu orogun ninu rẹ̀ pẹlu Èmi Ọlọhun, Emi yóò fi òun àti orogun rẹ̀ sílẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju emi n bọpabọsẹ lọ si ọdọ Ọlọhun pe ki n ní ọrẹ aayo kan laarin yin, nitori pe Ọlọhun Ọba Aleke ọla ti mú mi ní ọrẹ aayo gẹgẹ bi O ti mu Ibrahim ni ọrẹ aayo
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Ọlọhun maa n jowu, ati pe dajudaju olugbagbọ naa maa n jowu, owu jijẹ Ọlọhun ni ki olugbagbọ maa ṣe nnkan ti Ọlọhun ṣe ni eewọ fun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹnikẹni tí ó bá fi ohun miran búra yatọ si Ọlọhun Allah, onitọhun ti ṣe aigbagbọ tabi ka ní ó ti ṣẹbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju irun ti o wuwo ju fun awọn munaafiki ni irun Ishai ati Asunbaa, ka ni wọn mọ nkan ti n bẹ ninu rẹ - ni ẹsan – ni, wọn o ba wa ki i koda ki o jẹ ni irakoro
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju ninu awọn eniyan ti o buru julọ ni ẹni ti ọjọ igbedide ba ba ti wọn si wa ni alààyè, ati ẹni ti o ba mu awọn saare ni mọsalasi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju nnkan ti mo n bẹru julọ nipa yin ni ẹbọ kekere" wọn sọ pe: Ki ni ẹbọ kekere irẹ ojiṣẹ Ọlọhun? O sọ pe: "Ṣekarimi ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ má ṣe yìn mi jù gẹgẹ bi awọn Kristẹni ṣe yin ọmọ Maria jù; ẹrú Ọlọhun ni ẹmi n ṣe, nitori naa, ẹ wi pe: Ẹru Ọlọhun ati Ojiṣẹ Rẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹnití ó maa ṣoriire jù pẹlu ìṣìpẹ̀ mi ní ọjọ Igbende, oun ni ẹniti ó bá sọ pé ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, tí ó ṣo bẹẹ pẹlu ododo lati inu ọkàn rẹ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọlọhun a mu u wọ al-jannah lori èyíkéyìí iṣẹ ti o ba wa lori rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹniti ó bá pade Ọlọhun ni ẹniti kò mú orogun kankan pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Alujanna, ṣugbọn ẹniti ó bá pade Rẹ̀ ni ẹniti ó mú orogun pẹlu Rẹ̀, onitọhun yoo wọ Ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ku ti o si n pe akẹgbẹ kan ti o yàtọ̀ si Ọlọhun, o maa wọ ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn alakatakiti ti parun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni ti o ba lọ onigbese lára, tabi ti o ba a din in ku tabi ki o ni ki o ma san an mọ́, Ọlọhun maa fi i sábẹ́ ibòji Ìtẹ́-ọlá Rẹ̀ ni Ọjọ́ Àjíǹde, ni ọjọ́ ti ko nii si ibòji kankan àyàfi ibòji Rẹ̀”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni tí Ọlọhun ba fẹ oore fún, O maa fi àdánwò kàn án”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ fi mi sílẹ̀ lópin ìgbà tí mo ba fi yin sílẹ̀, dajudaju nnkan ti o pa awọn ti wọn ṣáájú yin run ni ibeere wọn ati iyapa wọn si awọn anabi wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dájúdájú Ọlọhun ko nii wo àwòrán yin ati dúkìá yin, ṣùgbọ́n O maa wo ọkàn yin ati iṣẹ yin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Isilaamu ni ki o jẹ́rìí pe ko si ẹni tí ìjọsìn tọ si lododo ayafi Ọlọhun, ati pe Muhammad ni ojiṣẹ Rẹ, ki o maa gbe ìrun dúró, ki o maa yọ sàká, ki o maa gba aawẹ Ramadan, ki o maa ṣe hajj ti o ba ni ikapa ọ̀nà lọ si ibẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba da adadaalẹ kalẹ sinu alamọri wa yii ninu nnkan ti ko si nibẹ, wọn maa da a pada ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ̀yin ẹrusin Mi, Emi ṣe abosi ni eewọ fun ara Mi, Mo si ṣe e ni eewọ laarin yin, ẹ ma ṣe abosi si ara yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Irẹ ọmọkunrin yii, emi yoo kọ ọ ni àwọn ọrọ kan pe: Máa ṣọ́ Ọlọhun, yoo si daabo bo ọ. Maa ṣọ Ọlọhun, iwọ yoo ri I ni iwaju rẹ. Ti o ba beere, beere lọwọ Ọlọhun, ati pe nígbà tí o ba wa iranlọwọ, wa iranlọwọ Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Gbogbo ìjọ mi ni yoo wọ alujanna ayafi ẹni tí ó bá kọ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹnikẹ́ni tí ó bá fara wé àwọn ènìyàn kan jẹ́ ọ̀kan nínú wọn.”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu ẹṣẹ lo tobi julọ lọdọ Ọlọhun? O sọ pe: "Ki o wa orogun fun Ọlọhun ti o si jẹ pe Oun ni O ṣẹda rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Kò tọ́ fun ọmọniyan ki o yan ọmọ-ìyá rẹ lódì tayọ ọjọ́ mẹ́ta, àwọn méjèèjì maa pàdé, eléyìí maa wa gbúnrí, èyí naa maa gbúnrí, ẹni tí ó ni oore ju ninu awọn mejeeji ni ẹni tí ó bá kọ́kọ́ sálámọ̀”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni tí ó bá kó ìpalára ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìpalára ba oun naa, ẹni tí ó bá ko ìnira ba ẹlòmíràn, Ọlọhun maa ko ìnira ba oun naa”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju ẹ maa ri Oluwa yin gẹgẹ bi ẹ ṣe n ri òṣùpá yìí, ẹ o nii ri inira nibi riri rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dájúdájú Ọlọhun maa n lọ́ alabosi lára, titi ti yoo fi mu u ti ko si nii jẹ ki ó bọ́
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ṣe ki n gbe ọ dìde lori nnkan ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- gbe mi dìde lórí ẹ? Ma fi ère kan kan silẹ àfi ki o pa a rẹ, ma si fi sàréè ti o ga kan kan silẹ afi ki o jẹ ki o bá ilẹ̀ dọ́gba
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Kii ṣe ara wa ẹni ti o ba retí ìṣẹ̀lẹ̀ aburú láti ara nǹkan tabi ti wọn ba a ṣe e, tabi ẹni ti o ba pe apemọra imọ kọ̀kọ̀ tabi ti wọn sọ imọ kọ̀kọ̀ fun, tabi ẹni ti o ba sà sí èèyàn tabi ti wọn ba a sà sí èèyàn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni ti o ba lọ ba yẹmiwo kan ti o wa bi i leere nipa nnkan kan, wọn ko nii gba irun rẹ fun ogoji ọjọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni tí ó bá gba ìmọ̀ latara ìràwọ̀, onítọ̀hún ti gba ẹka kan ninu oògùn, bi o ba ṣe n lekun ninu imọ ìràwọ̀ naa ni kikọ oògùn rẹ naa ṣe maa lékún”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Igbagbọ jẹ ipin aadọrin ati nnkankan- tabi ọgọta ati nnkankan-, eyi ti o ni ọla julọ nibẹ ni gbolohun Laa ilaaha illallohu, eyi ti o kere julọ nibẹ ni mimu suta kuro lọna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ̀gbà ọrùn kan ti wọn fi okùn ọfà tín-ín-rín ṣe ko gbọdọ ṣẹku ni ọrun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan tabi ẹgba ọrun kan afi ki wọn ge e”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ẹni ti o ba sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOHU, ti o wa ṣe aigbagbọ pẹlu nnkan ti wọn n jọsin fun yatọ si Ọlọhun, dukia rẹ ati ẹjẹ rẹ ti jẹ eewọ, ati pe ìṣirò rẹ wa lọ́wọ́ Ọlọhun”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn olùṣe ikẹ, Ọlọhun Ajọkẹ aye maa kẹ wọn, ẹ maa kẹ awọn ti n bẹ lori ilẹ, Ọba ti n bẹ ni sanmọ a kẹ ẹyin naa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọrọ yẹn ninu ododo ti alujannu n ji gbọ ni o wa, yoo waa gbe e si eti aayo rẹ gẹgẹ bi adiyẹ ṣe maa n gbe ọrọ fun adiyẹ miran, nigba naa ni wọn o waa ro irọ to le ni ọgọrun-un mọ ọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si ẹni kankan ti o n jẹrii pe ko si ẹni ti ijọsin tọ si lododo afi Allahu, ati pe Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni lododo lati inu ọkan rẹ, afi ki Ọlọhun ṣe ina leewọ fun un
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ ma ṣe jokoo si ori awọn sàréè, ẹ ko si gbọdọ kirun si i lara
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn wọnyẹn ni ìjọ kan, ti ẹru rere ba ku ninu wọn tabi ọkùnrin rere, wọn maa kọ mọsalasi kan sori saare rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọn mọ Isilaamu pa lori nkan márùn-ún
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ri ibajẹ kan ninu yin, ki o yi i pada pẹlu ọwọ rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ahọn rẹ, ti ko ba ni ikapa ìyẹn, ki o yi i pada pẹlu ọkan rẹ, ati pe ìyẹn ni o lẹ julọ ninu igbagbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ṣe daadaa ninu Isilaamu wọn ko nii ba a wí nípa nnkan ti o ṣe ni asiko aimọkan, ati pe ẹni ti o ba ṣe aburu ninu Isilaamu wọn maa ba a wí nípa akọkọ ati igbẹyin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Fun mi ni iro nipa ti mo ba ki awọn irun ọran-anyan, ti mo gba awẹ Ramadan, ti mo ṣe ẹtọ ni ẹtọ, ti mo ṣe eewọ ni eewọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Imọra ni idaji igbagbọ, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH maa n kun òṣùwọ̀n, ati pe sisọ gbolohun ALHAMDULILLAH ati gbolohun SUBHAANALLAH, mejeeji maa n kun- tabi o n kun- nnkan ti o n bẹ laaarin sanmọ ati ilẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ tẹti ẹ gbọ, o ṣee ṣe ki arakunrin kan, ki hadisi nipa mi de etigbọọ rẹ ti o si rọgbọku ni ori ibusun rẹ, ki o wa maa sọ pe: Iwe Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju iwọ Ọlọhun lori awọn ẹrusin ni ki wọn maa jọsin fun Un ki wọn si ma da nnkan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba ku ti ko da ẹbọ kankan pọ mọ Ọlọhun yoo wọ alujanna, ẹni ti o ba si ku ti o da ẹbọ pọ mọ Ọlọhun yoo wọ ina
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
sọ ọrọ kan fun mi ninu Isilaamu ti mi ko nii bi ẹnikẹni leere nípa rẹ yàtọ̀ si ẹ, o sọ pe: "Sọ pe: Mo gbagbọ ninu Ọlọhun, lẹyin naa ki o duro deedee
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju Ọlọhun maa ya arákùnrin kan sọ́tọ̀ nínú ìjọ mi lójú àwọn ẹ̀dá ni ọjọ́ igbende alukiyaamọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Nígbà tí Ọlọhun da alujanna ati ina, O ran Jibril- ki ọla
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọlọhun kọ kadara awọn ẹda ṣíwájú ki O to da sanmọ ati ilẹ fun ẹgbẹrun lọ́nà aadọta ọdun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju adehun ti o wa laaarin wa ati laaarin wọn ni irun, ẹni ti o ba gbe e ju silẹ, dajudaju o ti ṣe aigbagbọ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- kọ fun yin lati maa bura pẹlu awọn baba yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Akọkọ nnkan ti wọn maa ṣe idajọ rẹ laaarin awọn eniyan ni ọjọ igbedide ni nibi awọn ẹjẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju wọn n jẹ awọn mejeeji niya lọwọ, wọn o si jẹ wọn niya nitori alamọri nla kan (ni iwoyesi awọn eeyan), ẹ o wa ri ọkan ninu awọn mejeeji o jẹ ẹni ti kii mọra kuro nibi itọ, amọ ẹnìkejì o jẹ ẹni ti maa n gbé ọrọ ofofo kaakiri
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ṣé ki n sọ ọrọ kan fun yin nipa dajjal, ti Anabi kan ko sọ nipa rẹ ri fun ijọ rẹ? O jẹ olójú kan, o maa mu nnkan ti o da bii alujanna ati ina wa pẹlu rẹ,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ yára si awọn iṣẹ daadaa siwaju ki awọn fitina kan ti yio da bii oru ti o ṣokunkun gan o to de,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ ko gbọdọ sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ ati ti lagbaja ba fẹ, ṣùgbọ́n ẹ maa sọ pe: Ti Ọlọhun ba fẹ lẹyin naa ti lagbaja ba fẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju ẹ ma maa tẹle oju ọna awọn ti wọn ṣáájú yin, ni odiwọn ìbú atẹlẹwọ si ibu atẹlẹwọ, ni odiwọn apa si apa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba pepe lọ si ibi imọna, iru awọn ẹsan ti o n bẹ fun ẹni ti o ba tẹle e, maa wa fun un ninu ẹsan, ti ìyẹn ko nii din nnkan kan ku ninu awọn ẹsan wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni, fifi ẹyẹ furamọ aburu ati oore ẹbọ ni,- lẹẹmẹta-", ko si ninu wa afi, ṣùgbọ́n Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- n mu u lọ pẹlu igbarale Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ni a wa sọ pe: Iwọ ni olowo wa, ni o wa sọ pe: "Allāhu ni Olowo", a sọ pe: ati ọlọlajulọ inu wa, ati ọlọrọ julọ inu wa, ni o wa sọ pe: «Ẹ maa sọ awọn ọrọ yin, tabi apakan awọn ọrọ yin, ẹ ma jẹ ki esu o lo yin (ki o gbe yin kọja aala)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹyin eniyan, ẹ ṣọ́ra kuro nibi aṣeju nibi ẹsin, dajudaju nnkan ti o pa àwọn ti wọn ṣíwájú yin run ni aṣeju nibi ẹsin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ko si akoran, ko si si ifi ẹyẹ fura mọ daadaa tabi aburu, ati pe mo fẹ́ràn fah'lu, o sọ pe wọn sọ pe: Kí ni fah'lu? O sọ pe: "Ọrọ ti o daa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dajudaju o sọ nipa awọn Ansar pe: "Ẹnikan ko nii nífẹ̀ẹ́ wọn afi olugbagbọ, ẹnikan ko si nii korira wọn afi sobẹ-ṣelu, ẹni ti o ba nífẹ̀ẹ́ wọn, Ọlọhun maa nifẹẹ rẹ, ẹni ti o ba si korira wọn Ọlọhun maa korira rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
”O ti jere ti o ba sọ ododo”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Eyi ti o loore julọ ninu ọjọ ti oorun yọ nibẹ ni ọjọ Jímọ̀
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
lori ki ni a maa ṣadehun fun ẹ? O sọ pe: "Lori pe ẹ ma maa jọsin fun Ọlọhun ẹ ko si gbọdọ da nnkan kan pọ mọ Ọn, ati awọn irun maraarun-un, ẹ si gbọdọ maa tẹle- o wa sọ ọrọ kan ti o pamọ ni jẹjẹ- ẹ ko si gbọdọ beere nnkan kan lọwọ awọn eniyan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Musulumi ti wọn ba bi i leere ninu saare: O maa jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu ati pe dajudaju Muhammad ojisẹ Ọlọhun ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọn pa mi láṣẹ lati ba awọn eniyan ja titi wọn maa fi jẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Allahu, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ti wọn si n gbe irun duro, ti wọn si n yọ saka
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹsẹ mejeeji ẹru kan ko nii yẹ ni ọjọ igbedide titi ti wọn o fi bi i nipa ọjọ ori rẹ nibo ni o pari rẹ si, ati nipa imọ rẹ kini o fi ṣe, ati nipa dukia rẹ nibo ni o ti ko o jọ ati pe nibo ni o na an si, ati nipa ara rẹ nibo ni o lo o si
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Apejuwe awọn Mumuni nibi nini ifẹ ara wọn ati kikẹ ara wọn ati nini aanu ara wọn da gẹgẹ bi apejuwe odidi ara, nigba ti orike kan ba n ke irora gbogbo ara yoku ni yio para pọ pẹlu rẹ nibi aisun ati igbona
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mumini alagbara ni oore o si tun jẹ ẹni ti Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si ju Mumini ọlẹ lọ, ọkọọkan wọn si ni oore wa lara rẹ,
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
mo wa fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, ẹ o maa tẹle ilana awọn ti wọn ṣaaju yin
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Arakunrin kan wa si ọdọ Anabi Ọlọhun -ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-, o si ba a sọrọ nipa ọrọ kan, o sọ pe: “Ohunkohun ti Ọlọhun ba fẹ, ti iwọ anabi si fẹ. ” Nígbà náà ni Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, wí pé: “ṣé iwọ o fi mí ṣe bakannaa pẹlu Ọlọ́run ni? Sọ pé: Ohunkóhun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá fẹ́”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o maa le koko julọ ninu awọn eniyan ni ti iya ni ọjọ igbedide ni awọn ti wọn n ṣe afijọ ẹda Ọlọhun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọmọ Adam pe Mi ni opurọ, ko si tọ fun un, o si bu mi, ko si tọ fun un
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba mu aayo mi ni ọta, Mo ti kede ogun pẹlu rẹ, ati pe ẹru Mi o nii sunmọ Mi pẹlu nkankan ti Mo nífẹ̀ẹ́ si ju nkan ti Mo ṣe ni ọranyan fun un lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba sọ agbekọ, o ti ṣe ẹbọ (mu orogun pẹlu Ọlọhun)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn malaika o nii maa bẹ pẹlu ikọ kan ti aja ati agogo ba wa pẹlu wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Musulumi ni ẹni ti awọn musulumi la nibi ahọn rẹ ati ọwọ rẹ, ati pe Al-muhaajiru ni ẹni ti o yan nkan ti Ọlọhun kọ lodi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ko fi ọjọ kan sọ pé: Irẹ Oluwa mi, fori awọn àṣìṣe mi jin mi ni ọjọ ẹsan
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Njẹ ẹ mọ nnkan ti Oluwa yin sọ?” Wọn sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ rẹ ni wọn ni imọ julọ, o sọ pe: “O n bẹ ninu awọn ẹru Mi ẹni ti o ji ni onigbagbọ ati ẹni tí o ji ni alaigbagbọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju a n ri ninu ẹ̀mí wa nnkan ti ẹnikẹni nínú wa ko lee sọ ọ, o sọ pe: “Ṣé ẹ ti ri i?” Wọn sọ pé: Bẹẹni, o sọ pe: “Iyẹn ni igbagbọ ododo ti ko rùjú
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
ọpẹ ni fun Ọlọhun ti O da ete rẹ pada si royiroyi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Èṣù a maa wa ba ẹnikan ninu yin, yoo si sọ pe: Ta ni o ṣẹda èyí? Ta ni o ṣẹda èyí? Titi yoo fi sọ pé: Ta ni o ṣẹda Oluwa rẹ? Ti o ba ti ba a de ibẹyẹn, ki o yaa wa iṣọra pẹlu Ọlọhun ki o si jawọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju Ọlọhun ko nii ṣe abosi olugbagbọ kan ni ti daadaa ti o ba ṣe, wọn yoo fun un ni ẹsan rẹ ni aye, wọn si tun maa san an ni ẹsan pẹlu rẹ ni ọrun
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
O gba Isilaamu lori nnkan ti o ṣáájú ninu daadaa”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Apejuwe ṣọbẹ-ṣelu da gẹgẹ bii apejuwe aguntan ti o n lọ ti o n bọ laaarin agbo aguntan meji, yoo lọ sibi fun ìgbà kan, yoo tun lọ si ọ̀hún nigba mii”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju igbagbọ maa n gbó ninu ikun ẹni kọọkan yin gẹgẹ bí aṣọ ṣe maa n gbó, ki ẹ ya maa beere lọdọ Ọlọhun lati sọ igbagbọ di tuntun ninu awọn ọkan yin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ni ki wọn ka imọ kúrò nílẹ̀, ki aimọkan si pọ, ki ṣina si pọ, ti ọti mimu si maa pọ, ti onka awọn ọkunrin si maa kere, ti onka awọn obinrin si maa pọ titi ti o fi maa jẹ pe ọkùnrin kan ni yoo maa bẹ fun aadọta obinrin”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọjọ igbedide ko nii to titi ti arakunrin o fi maa kọja nibi saare arakunrin, o maa sọ pé: Mii ba si wa ni ipo rẹ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọjọ igbende ko nii to titi ẹ fi maa ba awọn Juu ja, titi okuta ti Juu wa lẹyin rẹ fi maa sọ pé: Irẹ Musulumi, eleyii ni Juu lẹyin mi, pa a”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, o maa ku díẹ̀ ki ọmọ Maryam sọkalẹ si aarin yin ni adajo oluṣedeedee, ti o maa run agbelebuu, ti o maa pa ẹlẹ́dẹ̀, ko nii jẹ ki wọn san isakọlẹ mọ, ti owo maa pọ̀ titi ẹni kankan ko fi nii gba a mọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Aye o nii parẹ titi ti igba o fi sunmọ ara wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ọlọhun a gba ilẹ mu, yoo si tun ka sanmọ pẹlu ọwọ ọtun Rẹ, lẹyin naa ni Yoo waa sọ pe: Emi ni Ọba, gbogbo ọba (olukapa) ori ilẹ̀ da?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Abàtà mi, ìrìn oṣù kan ni, omi rẹ̀ funfun ju wàrà lọ, òórùn rẹ̀ dùn ju alumisiki lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Maa wa nibi adágún naa ki n le ri ẹni tí o maa wa si ọdọ mi ninu yin, wọn maa mu awọn èèyàn kan kúrò ni tòsí ọdọ mi, mo maa wa sọ pé: Irẹ Oluwa mi, ara ìjọ mi ni wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Mo fi Ẹni tí ẹmi Muhammad wa lọ́wọ́ Rẹ bura, àwọn ife ìmumi rẹ pọ̀ ju onka awọn irawọ sanmọ lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Wọn maa mu ikú wá ni ìrísí àgbò ti o ni dúdú ati funfun lára
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Iná yin jẹ ẹ̀yà kan nínú ẹ̀yà àádọ́rin ti ina Jahannama ni
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba wa sọrọ, olódodo ni, ẹni tí a sọ òdodo fún si ni: “Wípé wọ́n maa kó ẹ̀dá ẹnikan nínú yín jọ sínú ikùn ìyá rẹ̀ fún ogójì ọjọ́
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Gbogbo nnkan pẹlu kádàrá ni, titi dórí ikagara ati ijafafa, tàbí ijafafa ati ikagara”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Ti Ọlọhun ba kádàrá fun ẹrú kan pé o maa kú si ilẹ̀ kan, O maa jẹ ki o ni bukaata si i.”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
emi ni Dimaam ọmọ Tha’labah, láti ìdílé Banuu Sahd ọmọ Bakr
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ nǹkan kan, o wa sọ pé: “Ìyẹn nigba ti imọ bá lọ
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹ má gba ọ̀rọ̀ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, ki ẹ sọ pé: {A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa}
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Awọn Juu ni awọn ti a binu si, ti awọn Nasara jẹ awọn ẹni anu
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Wọ́n maa ṣírò ijanba ti wọn ṣe fun ẹ, ati bi wọn ṣe yapa àṣẹ rẹ, ati irọ́ ti wọn pa fun ẹ, ati ìyà ti o fi jẹ wọn
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Njẹ Ẹni tí Ó mu un rìn lori ẹsẹ méjèèjì ni ayé ko ni ikapa lati jẹ ki o fi ojú rẹ rìn ni Ọjọ́ Àjíǹde ni?
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Sọ pe: LAA ILAAHA ILLALLOOH, maa fi jẹ́rìí fun ọ ni Ọjọ́ Àjíǹde
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Dajudaju nkan ti o n sọ ti o si n pepe si, nkan ti o daa ni, ti o ba fun wa niroo pe aforijin n bẹ fun nkan ti a ṣe
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Lọ ba a ki o si sọ fun un pe: Dajudaju irẹ ko si ninu awọn ọmọ ina, ṣugbọn o wa ninu awọn ọmọ alujanna
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
(Thumma latus alunna yauma-izin ‘anin na’eem)
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
“Awọn eniyan kan maa wa ni igbẹyin ijọ mi, ti wọn maa maa sọ fun yin nnkan ti ẹyin gangan tabi awọn baba yin ko gbọ, ẹ ṣọra fun wọn ”
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Maa kọ, mo fi Ẹni ti ẹmi mi n bẹ lọwọ Rẹ bura, nkankan o nii jade nibẹ (ẹnu rẹ) ayaafi ododo
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ti ẹ ba ti gbọ oluperun ki ẹ yaa maa sọ gẹgẹ bi o ṣe n sọ, lẹyin naa ki ẹ wa ṣe asalaatu fun mi
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Iyẹn ni Shaitan kan ti wọn n pe ni Khinzab, ti o ba ti fura mọ ọn, ki o wa iṣọra pẹlu Ọlọhun kuro lọdọ rẹ, fẹ atẹgun si ẹgbẹ osi rẹ lẹẹmẹta
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu
Ẹni ti o ba kọ oju ija si wa pẹlu ohun ìjà, ko kii ṣe ara wa
عربي Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu