+ -

عَنْ ‌أَبِي هُرَيْرَةَ رَضِيَ اللهُ عَنْهُ قَالَ:
كَانَ أَهْلُ الْكِتَابِ يَقْرَؤُونَ التَّوْرَاةَ بِالْعِبْرَانِيَّةِ، وَيُفَسِّرُونَهَا بِالْعَرَبِيَّةِ لِأَهْلِ الْإِسْلَامِ، فَقَالَ رَسُولُ اللهِ صَلَّى اللهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ: «لَا تُصَدِّقُوا أَهْلَ الْكِتَابِ وَلَا تُكَذِّبُوهُمْ، وَقُولُوا: {آمَنَّا بِاللهِ وَمَا أُنْزِلَ إِلَيْنَا} [البقرة: 136] الْآيَةَ».

[صحيح] - [رواه البخاري] - [صحيح البخاري: 4485]
المزيــد ...

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe:
Awọn Juu ati Kristẹni maa n ka Taoreeta pẹ̀lú èdè Hébérù, wọn si maa n túmọ̀ rẹ pẹlu èdè Lárúbáwá fun awọn Mùsùlùmí, ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: “Ẹ má gba ọ̀rọ̀ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, ki ẹ sọ pé: {A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa} [Al-Baqarah: 136] Aayah”.

[O ni alaafia] - [Bukhaariy gba a wa] - [Sọhiihu ti Bukhaariy - 4485]

Àlàyé

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ fun awọn ìjọ rẹ láti ṣọ́ra fun gbigba ẹtan pẹ̀lú nǹkan ti àwọn Júù àti Kristẹni n gbà wá nínú àwọn ìwé wọn, Níbi tí àwọn Júù ìgbà ayé Ànábì máa ń ka Taoreeta ní èdè Hébérù. Ó jẹ́ èdè àwọn Júù, wọ́n sì túmọ̀ rẹ̀ ní èdè Lárúbáwá, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa sọ pé: Ẹ ma gba ọrọ àwọn Júù àti Kristẹni ni ododo, ẹ si ma pe e ni irọ, èyí níbi ohun ti a ko mọ ododo rẹ yatọ si irọ rẹ; Torí pé Ọlọhun ti ọla Rẹ ga pa wa láṣẹ ki a ni igbagbọ ninu Kuraani ati Ìwé ti wọn sọ̀kalẹ̀ fun wọn, ṣùgbọ́n ko si bi a ṣe fẹ mọ èyí tí ó ni àlàáfíà ninu ohun ti wọn n sọ nipa awọn Ìwé sánmọ̀ yẹn yatọ si èyí tí kò ni àlàáfíà; tori ko wa ninu ṣẹria wa ohun ti o maa ṣàlàyé ododo rẹ yatọ si irọ rẹ, Nítorí náà a maa kóra ro, a ko nii gba ọrọ wọn ni ododo; ki a ma baa kópa pẹ̀lú wọn nibi ohun ti wọn yi padà ninu ẹ, a ko si nii pe ọrọ wọn ni irọ; bóyá o le jẹ òdodo, ki a ma baa lọ tako ohun ti wọn pa wa láṣẹ ki a gbagbọ, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa pa wa láṣẹ ki a sọ pé: “A gbàgbọ́ nínú Allāhu àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún wa àti ohun tí Wọ́n sọ̀kalẹ̀ fún (àwọn Ànábì) ’Ibrọ̄hīm, ’Ismọ̄‘īl, ’Ishāƙ, Ya‘ƙūb àti àwọn àrọ́mọdọ́mọ Ya‘ƙūb. (A gbàgbọ́ nínú) ohun tí Wọ́n fún (àwọn Ànábì) Mūsā àti ‘Īsā, àti ohun tí Wọ́n fún àwọn Ànábì (yòókù) láti ọ̀dọ̀ Olúwa wọn. A kò ya ẹnì kan sọ́tọ̀ nínú wọn. Àwa sì ni mùsùlùmí (olùjuwọ́-jusẹ̀ sílẹ̀) fún Un.” [Al-Baqarah: 136].

Ìtumọ̀ sí èdè mìíràn: Èdè Gẹ̀ẹ́sì Èdè Urdu Èdè Sípéènì Èdè Indonéṣíà Èdè Uyghur Èdè Bangali Èdè Faransé Èdè Tọ́kì Èdè Rọ́ṣíà Èdè Bosnia Èdè Sinhala Èdè India Èdè Vietnamese Èdè Tagalog Ti Kurdish Èdè Hausa Ti Pọtuga Malayalam Èdè Telgu Ti èdè Sawahili Tamil Burmese Thai Ede Jamani Pashto Assamese Ede Alibania Titi Sweden Ìtumọ̀ sí èdè Amharic Ìtumọ̀ sí èdè Dutch Titi èdè Gujarat Ti èdè Kyrgyz Ti èdè ìlú Nepal Ti èdè Lithuania Ti èdè Dari Ti èdè ìlú Serbia Ti èdè Somalia Ti èdè ìlú Tajikistan Ti èdè Rwanda Ti èdè ìlú Romania Ti èdè ilu Hungary Ti èdè Czech الموري Ti ede Madagascar Ti ede ilu Italy Ti èdè ẹ̀yà Oromo Ti èdè Kannada الولوف البلغارية Ti ede Azerbaijan اليونانية Ti èdè ilu Uzbekistan Ti èdè ìlú Ukraine الجورجية اللينجالا المقدونية
Ṣíṣe àfihàn àwọn ìtumọ̀ sí èdè mìíràn

Lára àwọn àǹfààní hadiisi naa

  1. Mẹta ni ohun ti àwọn Júù àti Kristẹni sọ pin si: Ìpín kan wa ti o ba Kuraani ati Sunna mu, a maa gba a lododo, ìpín kan yapa Kuraani ati Sunna, irọ ni èyí, a ko nii gba a lododo, ìpín kẹta ni eyi ti ko si ohun ti n tọka si òdodo rẹ tabi irọ rẹ ninu Kuraani ati Sunna, a maa gba a wa, ṣùgbọ́n a ko nii gba a lododo, a ko si nii pe e ni irọ.