عَنْ جَابِرِ بْنِ عَبْدِ اللَّهِ رضي الله عنهما أَنَّ النَّبِيَّ صَلَّى اللَّهُ عَلَيْهِ وَسَلَّمَ قَالَ:
«لَا تَعَلَّمُوا الْعِلْمَ لِتُبَاهُوا بِهِ الْعُلَمَاءَ، وَلَا لِتُمَارُوا بِهِ السُّفَهَاءَ، وَلَا تَخَيَّرُوا بِهِ الْمَجَالِسَ، فَمَنْ فَعَلَ ذَلِكَ، فَالنَّارُ النَّارُ».
[صحيح] - [رواه ابن ماجه] - [سنن ابن ماجه: 254]
المزيــد ...
Láti ọ̀dọ̀ Jaabir ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé:
“Ẹ ma kọ́ imọ lati le maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, tabi lati le baa maa fi ja àwọn omugọ níyàn, ẹ si ma ṣẹsa lati wa ni iwájú ni àwọn àpéjọ pẹ̀lú ẹ, ẹni tí ó bá ṣe iyẹn, iná ni, iná ni”.
[O ni alaafia] - [Ibnu Maajah ni o gba a wa] - [Sunanu ti Ibnu Maajah - 254]
Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kilọ kúrò nibi wiwa imọ lati maa fi ba àwọn onimimọ ṣe iyanran, ati lati le fi hàn pé onimimọ bii tiyín ni èmi náà, tabi lati fi ba àwọn omugọ ati awọn ti làákàyè wọn lẹ sọ̀rọ̀ lati ba wọn jiyàn, tabi ki o kọ imọ lati wa ni iwájú ni àpéjọ, ti wọn si maa ti i saaju ẹlòmíràn nibẹ. Ẹni tí ó bá ṣe iyẹn; o ni ẹtọ si iná pẹlu ṣekarimi rẹ ati àìní imọkanga nibi wiwa imọ naa nítorí Ọlọhun.